Eeyan mẹtadinlogun ti gba fọọmu lati dije dupo aarẹ ninu ẹgbẹ APC

Jọkẹ Amọri

Fọọmu sipo aarẹ fun ẹgbẹ APC ti fẹẹ da bii piọ wọta bayii, iyẹn omi inu ọra pẹlu bo ṣe jẹ pe taja-tẹran lo n gba fọọmu naa, ti gbogbo wọn fẹẹ dupo aarẹ ẹgbẹ naa pẹlu bi owo fọọmu wọn ṣe wọn to. Ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un miliọnu Naira ni oludije kọọkan yoo gba fọọmu.
Laarin ọjọ meji sira wọn, awọn bii marun-un ni wọn gba fọọmu labẹ asia ẹgbẹ APC lati dupo naa.
Ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi, jade, to si gba fọọmu lati dupo aarẹ lorukọ ẹgbẹ APC.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni gomina ipinlẹ Ogun tẹlẹ, Ibikunle Amosun ati Pasitọ Tunde Bakare, naa gba fọọmu lati dupo aarẹ.
Bakan naa ni gomina ipinlẹ Zamfara tẹlẹ, Sanni Yerima, naa ti gba fọọmu ninu ẹgbẹ APC yii kan naa.
Gomina Banki Apapọ ilẹ wa, Godwin Emefiele, paapaa ko gbẹyin, oun naa ti gba fọọmu miliọnu lọna ọgọrun-un Naira ti ẹgbẹ APC n ta a fawọn oludije. Bakan na ni Minisita fun imọ ẹrọ ati sayẹnsi nilẹ wa, Ogbonnaya Onu, ti gba fọọmu tiẹ naa.
Ta a ba ka a leni eji, o ti n lọ si bii awọn mẹtadinlogun ni wọn ti gba fọọmu bayii, ipo ẹyọ kan naa ni gbogbo wọn si n mura lati du ninu ibo abẹle ẹgbẹ naa ti yoo waye lọgbọnjọ, oṣu Karun-un, yii.
Ọpọ eeyan lo ti n bu ẹnu atẹ igbesẹ ti awọn ẹgbẹ naa n gbe, ti wọn si n sọ pe ko ti i ṣẹlẹ ri latigba ta a ti bẹrẹ eto ijọba awa-ara-wa tuntun pe eeyan bii mẹtadinlogun yoo gba fọọmu lori ipo kan ṣoṣo ninu ẹgbẹ oṣelu kan naa, paapaa ju lọ, ipo aarẹ.
Bakan naa ni awọn eeyan n kọminu si owo tabua ti wọn fi n ra fọọmu naa. Ibeere ti wọn si n beere ni pe nibo ni awọn eeyan to fẹẹ dupo ọhun ti ri iru owo bayii, paapaa ju lọ nigba to jẹ pe oṣiṣẹ ijọba lo pọ ninu wọn.

Leave a Reply