Eeyan mẹtalelogun jona ku ni Kogi, odidi mọlẹbi kan wa ninu wọn

Manigbagbe ni  Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, jẹ fun awọn eeyan ipinlẹ Kogi latari ijamba ọkọ kan to gbina, to si mu ẹmi eeyan mẹtalelogun lọ lẹẹkan naa.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹjọ aarọ ni ajalu buruku naa ṣẹlẹ nigba ti ọkọ tanka epo kan sọ ijanu rẹ nu, to si lọọ kọlu awọn ọkọ to n lọ jẹẹjẹ wọn lagbegbe Felele, loju ọna  to lọ si Lọkọja si Okene ati Abuja, to si gbina loju ẹsẹ.

Awọn tisẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe lati Okene ni dẹrẹba tanka kan to kun fun bẹntiroolu ti n bọ, lojiji ni bireeki rẹ daṣẹ silẹ, eyi to mu ko lọọ kọ lu awọn ọkọ to n bọ. Bo ṣe sọ lu wọn lo gbina lesekẹsẹ, kawọn eeyan si too mọhun to n ṣẹlẹ, ọpọlọpọ mọto lo ti gbina, tina ọhun si ran mọ awọn to n kọja lọ. Ọpọlọpọ awọn to wa ninu mọto yii ni ko raaye jade, ti ina si jo wọn pa mọ inu ọkọ nibẹ.

Awọn mẹfa ti wọn jẹ odidi idile kan ti wọn wa ninu ọkọ Toyota Sienna kan la gbọ pe wọn jona ku patapata. Iṣẹlẹ naa ko yọ awọn akẹkọọ Poli ipinlẹ naa atawọn ọmọleewe ti wọn n gbe lọ sileewe wọn silẹ. Bẹẹ lawọn to wa nitosi ti wọn n rin lọ paapaa fara gba ninu iṣẹlẹ aburu naa.

Ọga awọn ẹṣọ oju popo (FRSC) nipinlẹ naa, Idris Alli, sọ pe tanka epo kan, bọọsi to n ko awọn ọmọleewe lọ, ọpọlọpọ ọkọ ayọkẹle ati kẹkẹ NAPEP pẹlu ọkada lo fara gba ninu iṣẹlẹ naa. Ọkunrin naa ni eeyan mẹtalelogun lo jona kọja bo ṣe yẹ. Akẹkọọ kan ṣoṣo ni wọn lo mori bọ ninu ọkọ ileewe naa, ṣugbọn ẹsẹ-kan-aye ẹsẹ-kan-ọrun loun naa wa.

Ọpọlọpọ iwe, bata awọn ọmọleewe ati baagi ileewe lo kun ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye nitori o jẹ asiko tawọn ọmọleewe n lọ sileewe.

ALAROYE gbọ pe awọn alaṣẹ ileewe Baptist Group of Sachools, to wa lorita Ganaja, nipinlẹ naa, ti ti ileewe naa pa lati fi ṣọfọ awọn akẹkọọ wọn to padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ naa.

 

Leave a Reply