Monisola Saka
Lẹyin ija nla to bẹ silẹ laarin awọn eeyan Ilajẹ ti wọn n ṣiṣẹ apẹja atawọn ẹya Ibeno, n’Ipinlẹ Akwa-Ibom, ijọba ipinlẹ ọhun ti kede konile-o-gbele lagbegbe naa.
Ko din ni eeyan mẹwaa ni wọn ti padanu ẹmi wọn, nigba ti awọn mi-in ti dawati, ti wọn si ni dukia to to aimọye miliọnu Naira ti ṣofo lakooko ija ọhun.
Lasiko konile-o-gbele ọhun, ko ni i si lilọ bibọ awọn eeyan ati ọkọ lagbegbe Riverside, laarin aago meje alẹ si mẹfa aarọ gẹgẹ bi atẹjade latọwọ alaga ijọba ibilẹ Ibeno, Oloye Henry Mkpa, ṣe sọ. Atẹjade ọhun ti Akọwe iroyin rẹ, Ọgbẹni Melford Asuquo, buwọ lu lorukọ alaga kansu naa fawọn oniroyin ni Uyo, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ ọhun l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni wọn ti ṣekilọ pe ẹnikẹni tọwọ ba tẹ lakooko ti wọn ni ki wọn ma jade yoo fimu kata ofin.
O tẹsiwaju pe ofin tijọba ibilẹ ọhun gbe kalẹ waye latari ati dena ija miiran laarin awọn ẹya mejeeji tọrọ kan.
Ninu atẹjade ọhun ni wọn ti ni, “Pẹlu ija nla to bẹ silẹ laarin awọn ẹya Yoruba atawọn eniyan Mkpanak, nijọba ibilẹ Ibeno, eyi to ti mu ki ọpọ ẹmi ati dukia ṣofo, alaga ijọba ibilẹ ọhun ti kede konile-o-gbele lati irọlẹ titi daarọ ọjọ keji lai fakoko ṣofo titi di igba ti alaga ba fopin si aṣẹ to pa ọhun.
“Ni ibamu pẹlu ohun ti wọn sọ soke yii, ko ni i si lilọ bibọ eeyan ati ọkọ nibikibi laarin ijọba ibilẹ naa, wọn ti fi awọn ẹṣọ alaabo si awọn ibi kọọkan lati bẹrẹ iṣẹ lori ofin ọhun. Ẹnikẹni ti ọwọ ba ba laarin awọn akoko yii yoo da ara rẹ lẹbi”.
Igbakeji gomina ipinlẹ ọhun, Ọgbẹni Moses Ekpo, ti ṣabẹwo si agbegbe ibi ti ileeṣẹ Mobil wa ti wahala naa ti ṣẹlẹ lojuna ati wa ojutuu si rogbodiyan ọhun, ati lati wa ọna abayọ si ọrọ awọn ti ija naa ti sọ di alainile, ti wọn ti tibẹ waa dẹni to n sun kaakiri.