Eeyan mẹwaa ku ninu ijamba ọkọ ni Fidiwọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Bo tilẹ jẹ pe eeyan mẹrin ni ajọ FRSC ipinlẹ Ogun sọ pe wọn ku ninu ijamba ọkọ to waye laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlogun oṣu kin-in-ni yii, ni Fidiwọ, loju ọna marosẹ Eko s’Ibadan, awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe ko din leeyan mẹwaa to dagbere faye.

Ohun ti Kọmandanti Ahmed Umar, ọga FRSC ipinlẹ Ogun, sọ fawọn akọroyin ni pe ni nnkan bii aago mọkanla aarọ ku iṣẹju marun-un ni iṣẹlẹ aburu naa waye, ninu eyi ti eeyan mẹrin ti ku, ti awọn mejila si fara pa.

O ṣalaye pe ere asapajude ti dẹrẹba ọkọ Mazda ti nọmba e jẹ APP 111 XM n sa lo fa ijamba naa. Umar sọ pe ọkọ tanka kan lo n yipada lọwọ loju ọna ọhun, ki bọọsi to n sare buruku bọ naa too lọọ rọ lu u to si fi ẹmi awọn eeyan ṣofo, to tun ṣe awọn mi-in leṣe yanna-yanna.

Gẹgẹ bo ṣe wi, “ Eeyan mejila lo fara pa, ọkunrin mẹsan-an, obinrin mẹta. O ṣe ni laaanu pe eeyan mẹrin ku ninu ijamba naa, agbalagba ọkunrin ni gbogbo wọn.”

Ọga FRSC yii sọ pe ileewosan Victory ati Idẹra, l’Ogere, lawọn to ṣeṣe wa, nigba tawọn oku ti wa ni mọṣuari FOS, n’Ipara.

O waa kilọ fawọn awakọ, o ni ki wọn ro ti pe ọdun tuntun la tun wa yii, ki wọn yee wakọ lọna to n sọ ẹmi nu, to tun n sọ ọpọ eeyan di alaabọ ara.

Bẹẹ lo ba awọn teeyan wọn ba iṣẹlẹ naa lọ kẹdun, o ni ki wọn lọ si ileeṣẹ FRSC Ogunmakin fun ẹkunrẹrẹ alaye lori ijamba yii.

Leave a Reply