Eeyan mẹwaa ku, ọpọ fara pa, nibi ijamba ọkọ ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Kwara

O kere tan, eeyan mẹwaa ni wọn ti dagbere faye nibi ijamba ọkọ to waye niluu Kanbi, nijọba ibilẹ Moro, nipinlẹ Kwara, ti ọpọ si farapa yannayanna.

Alẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, ni ọkọ ero Toyota Hiace alawọ funfun ati ọkọ Ford alawọ omi aro digbo lu ara wọn. Ninu eeyan mọkandinlogun to wa ninu ọkọ mejeeji, mẹwaa lo ku loju ina, tawọn mẹsan-an yooku si fara pa yannayanna.

Gbogbo awọn to fara pa ni wọn ti ko lọ si ile iwosan ti wọn ko darukọ fun itọju to peye, ti wọn si ti ko awọn oku lọ si yara igbokuu-si nileewosan ile ẹkọ olukọni Fasiti Ilọrin (UITH).

Awọn tọrọ naa ṣoju wọn sọ pe dẹrẹba to wa ọkọ Toyota yii lo sare asapajude to fi kọ lu Ford to n bọ jẹẹjẹ rẹ.

Nigba ti a pe ọga agba ajọ ẹsọ alaabo oju popo (FRSC), ẹka ti ipinlẹ Kwara, Jonathan Owoade, o fidi iṣẹlẹ naa mulẹ pe dẹrẹba to wa Ford elero mejidinlogun mori bọ ninu ijamba ọhun, ati pe lati ilu Minna, nipinlẹ Niger, lo ti n bọ, to si n lọ si ilu Ọffa. O kọ lu ọkọ nla akẹru to ti bajẹ kalẹ soju popo.

Ọwọade ni eeyan mẹwaa ku loju-ẹṣẹ, ti awọn si ti ko awọn to fara pa lọ si ile iwosan, to fi mọ dẹrẹba to wa ọkọ naa, tawọn si ti ko oku lọ si yara igbokuu- si ni (UITH) Ilọrin.

Leave a Reply