Eeyan mọkanla ku sinu ijamba ọkọ lọna Isẹyin si Ṣaki

Ọlawale Ajao, Ibadan

Eeyan  mẹwaa lo ku iku ojiji ninu ijamba ọkọ kan to waye lọna ilu Isẹyin si Ṣaki lagbegbe Oke-Ogun ni ipinlẹ Ọyọ.

Ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, niṣẹlẹ ọhun waye nigba ti ọkọ bọọsi elero mejidinlogun (18) kan ati ọkọ ajagbe nla kan fori sọra wọn niluu kan ti wọn n pe ni Agúnrégé lọna Isẹyin si Ṣaki.

Ọkan ninu awọn tiṣẹlẹ yii ṣoju wọn fidi ẹ mulẹ pe oorun lo jọ pe awakọ bọọsi ọhun n sun lọwọ to fi kọlu ọkọ ajagbe ti wọn wa gunlẹ sibẹ jẹjẹ.

Loju ẹsẹ ni mọkanla ninu ero mẹtala to wa ninu mọto yii gbẹmi-in mi gẹgẹ bọkunrin naa ṣe sọ.

Oun naa lo fi kun un pe meji ninu awọn ero naa ni wọn ri gbe lọ sileewosan fun itọju nitori ti wọn fara pa yannayanna.

Adura lawọn mejeeji nilo ki wọn too le mori bọ ninu iku oro to pa awọn akẹgbẹ wọn ninu ijamba ori irinajo naa.

 

 

Leave a Reply