Eeyan mọkandinlogoji tun ko arun Korana lọjọ keji ọdun Keresi ni Kwara

Stephen Ajagbe, Ilorin

Eeyan mọkandinlogoji mi-in lo tun ti lugbadi arun Koronafairọọsi lọjọ keji ọdun Keresimesi nipinlẹ Kwara.

Eyi mu ki iye awọn to ti ko arun naa le ni ẹgbẹrun kan ati irinwo din diẹ (1,379), lara wọn, ẹgbẹrun le ọgọrun-un kan lo ti gbadun, awọn mejidinlaaadọsan-an (168), lo ṣi ni i bayii ti wọn n gbatọju.

Atajẹde kan ti Alukoro igbimọ to n gbogun ti arun Covid-19 ni Kwara, Rafiu Ajakaye, gbe jade lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, fi han pe eeyan mejilelọgbọn ni kinni ọhun ti pa.

Ẹwẹ, awọn esi ayẹwo ọgọsan ati mẹfa (186) ni wọn ṣi n reti.

O ṣalaye pe meje lara awọn to ti wa nibudo itọju arun naa lo ti tun gbadun, ti wọn si ti gba ile wọn lọ.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Nitori to ni oun yoo fopin si eto aabo ni Borno ati Yobe, PDP Ekiti sọrọ si Fayẹmi

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti Ẹgbẹ PDPipinlẹ Ekiti ti yẹgẹ ẹnu si gomina ipinlẹ Ekiti, Dokita Kayọde …

Leave a Reply

//ashoupsu.com/4/4998019
%d bloggers like this: