Eeyan mọkanla padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ ni Kwara

Stephen Ajagbe, Ilorin

Awọn arinrinajo mọkanla ni wọn padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii, nikorita ilu Ṣhao, nipinlẹ Kwara.

Ọga agba ajọ to n mojuto igboke-gbodo loju popo, FRSC, ẹka ipinlẹ Kwara, Jonathan Ọwọade, ṣalaye pe ere asapajude lo fa ijamba naa.

Ọwọade ni ni nnkan bii aago mẹfa aabọ aarọ Satide lawọn gba ipe kan pe ọkọ akero bọọsi pẹlu akẹru kan kọ lu ara wọn.

O tẹsiwaju pe laarin eeyan ogun to wa ninu awọn ọkọ naa, mẹsan-an pere lo mori bọ, ṣugbọn wọn fara pa, awọn mọkanla ni wọn jẹ Ọlọrun nipe.

Ọkunrin naa ni awọn ti ko awọn oku mọkanla naa lọ silewosan ẹkọṣẹ Fasiti Ilọrin, UITH, awọn to fara pa si wa nibi ti wọn ti n gbatọju nilewosan kan to wa nitosi ibi ti ijamba naa ti ṣẹlẹ.

Leave a Reply