EFCC fẹẹ mu Okorocha, oludije funpo aarẹ ẹgbẹ APC

Orẹlouwa Adedeji
Ajọ to n gbogun ti kiko owo ilu ati iwa ajẹbanu, EFCC, ti ṣabẹwo si ile gomina ipinlẹ Imo tẹlẹ to tun jẹ oludije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, Rochas Okorocha. Ile rẹ to wa niluu Abuja ni ajọ naa lọ, ti wọn si gẹgun de e bii kinihun to n wa ẹran to fẹẹ pa jẹ.
ALAROYE gbọ pe niṣe ni wọn n pooyi ile naa, gbogbo erongba wọn si ni lati mu gomina Imo tẹlẹ naa, ẹni ti ajọ yii lawọn ti fi iwe pe lati waa yọju si awọn, ṣugbọn to kọ ti ko dahun.
O jọ pe nitori pe ọkunrin naa ko jẹ ipe wọn ni wọn fi lọọ ka a mọle, ṣugbọn ko sẹni to le sọ boya wọn ba a ninu ile naa tabi ko si nibẹ.
Ọkan ninu awọn ọmọọṣẹ Okorocha sọ pe awọn eeyan ti wọn wọle wa, ti wọn fẹẹ mu Okorocha ko ni iwe aṣẹ lati ṣe bẹẹ.
O fi kun un pe awọn kan ni wọn n dunkooko mọ ọkunrin yii lati fi erongba rẹ lori ipo aarẹ to fẹẹ du silẹ.

Leave a Reply