EFCC gba awọn agunbanirọ nimọran: Ẹ yẹra fun iwa jibiti, o le ba ọjọ ọla yin jẹ

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣise owo ilu mọkumọku, EFCC, nilẹ yii, ti rọ awọn agunbanirọ lati jẹ aṣoju rere fun orile-ede Naijiria, lati ri i daju pe wọn n gbogun ti iwa jibiti  atawọn iwa ibajẹ mi-in to fara pẹ ẹ.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ni alaga ajọ ọhun nilẹ yii, Abdulrasheed Bawa, rọ awọn agunbanirọ naa, nigba to n ba wọn sọrọ ni ipagọ wọn to wa ni Yikpata, nijọba ibilẹ Ẹdu, nipinlẹ Kwara, o ni ki wọn takete si gbogbo ohun to ba jẹ mọ iwa jibiti ati iwa ibajẹ mi-in to fara pẹ ẹ. Ajọ naa sọrọ yii nibi eto kan ti wọn ṣe, ti wọn pe akori rẹ ni “EFCC, ati ipa wọn lori awọn ọdọ lati dẹkun lilu jibiti lori ẹrọ ayelujara” eyi to waye ni ipagọ wọn.

Alukoro ajọ EFCC, ẹka ti Ilọrin, Ayodele Babatunde to da wọn lẹkọọ ni ki awọn agunbanirọ naa tẹpa mọṣẹ wọn, tori pe atẹlẹwọ ẹni ki i tan ni jẹ, ati pe iwa jibiti lori ẹrọ ayelujara ko le gbe wọn de bi irẹ, yoo kan ba ọjọ ọla wọn jẹ ni, tori ibukun Ọlọrun ni i mu ni la, lai fi laalaa kun un. Bakan naa lo tun rọ wọn lati ran ajọ naa lọwọ nipa jijẹ oloootọ, ki wọn si jinna si jibiti lori ẹrọ ayelujara ati nnkan mi-in to fara pẹ ẹ.

 

 

Leave a Reply