EFCC mu babalawo meji at’awọn mi-in fẹsun jibiti n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Awọn ayederu oniṣegun ibilẹ meji kan, Toheeb Ajiṣafẹ ati Usman Ogundayọ, pẹlu awọn mẹrinlelogun (24) mi-in ti dero atimọle EFCC, ajọ to n gbogun ti jibiti ati iwa magomago n’Ibadan.

Jibiti ni wọn lawọn mẹrẹẹrindinlọgbọn (36) n lu awọn eeyan kakairi kọwọ ajọ EFCC too tẹ wọn lọjọ kọkandinlọgbọn (29), oṣu kẹwaa, ọdun 2021 yii.

Gẹgẹ bi Ọgbẹni Wilson Uwajaire ti i ṣe agbẹnusọ ajọ naa ṣe fidi ẹ mulẹ ninu atẹjade to fi ṣọwọ sawọn oniroyin nirọlẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, laduugbo Soka, n’Ibadan, lọwọ awọn agbofinro ti to wọn.

Orukọ diẹ ninu awọn mẹrinlelogun yooku Soyinka Emmanuel Oluwafẹmi, Ọlaoti Fawaz, Omoke Ogbonaya, Okhiria Alex, Ọlamilekan Ibrahim, Olagoke Olalekan, Adeniran Ibrahim Adeṣina, Ọlaṣupọ Temitayọ Ayọmide, Adeniran Basit, Ogunṣẹtan Gbọlahan Oluwaṣẹgun ati Balogun Salam Ọmọlade.

Akẹkọọ ileewe giga Lead City University, n’Ibadan, ni wọn pe mẹrin ninu wọn.

Orukọ awọn yooku ni Ilesanmi Mayọwa, Amao Emmanuel Abiọdun, Ọlakanmi Babatunde Abdulrahmon, Ọlaṣile Jide, Dauda Sodiq, Hammed Ayọmide Rasheed, Sodiq Ọlaide, Ọlamilekan Ibrahim, Idris Damilọla Yusuf, Abdulramon Mubarak ati Ogunbiyi Ṣẹgun.

Ọgbẹni Uwajaire sọ pe o pẹ diẹ ti awọn eeyan ti mu ẹsun awọn afurasi ọdaran wọnyi wa si ọfiisi ajọ EFCC, ẹka t’Ibadan, ṣugbọn ti awọn ko tete sọrọ naa sita faye gbọ nitori iwadii ijinlẹ ti awọn pinnu lati ṣe lori awọn ẹsun naa.

O ni ninu iwadii ọhun lo ti han gbangba pe gbogbo awọn afurasi mẹrẹẹrindinlọgbọn (36) yii ni wọn jẹbi ẹsun jibiti ti wọn fi kan wọn.

Pupọ ninu dukia ti awọn eeyan wọnyi ko jọ nidii iṣẹ jibiti ti wọn ni wọn yan laayo lawọn agbofinro ti gba lọwọ wọn fun ijọba.

Diẹ ninu awọn dukia wọn ọhun ni ọkọ ayọkẹlẹ olowo nla nla, tẹlifiṣan, ẹrọ agbeletan ti wọn n pe ni laputọọpu ati bẹẹ bẹẹ lọ.

 

Leave a Reply