EFCC mu Ọbasa, olori ile-igbimọ aṣofin Eko

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu basubasu (EFCC) ti mu Abẹnugan ile-igbimọ aṣofin Eko, Ọgbẹni Mudashiru Ọbasa.
Ẹsun ikowojẹ ati ṣíṣe owo ilu mọkumọku ni wọn ṣe torí ẹ lawọn fẹẹ rí lagọọ awọn.
Agbẹnusọ àjọ naa, Ogbẹni Wilson Uwujaren,sọ pe ni kete tawọn fi iwe pe e lo ti fẹsẹ ara ẹ rin wa, to si n dahun sì oríṣiiríṣi awọn ibeere lori ẹsun ikowojẹ ti wọn fi kan an.
Ṣaaju asiko yii ni wọn ti ka oríṣiiríṣi ẹsun si i lẹsẹ, to si n tẹnu mọ ọn pe wọn fẹẹ le oun nipo ni, oun ko mọ nípa ẹ rara.
Ọkan lara awọn ẹsun ọhun to sọ pe loootọ lo waye ni ti ọgọ́rin miliọnu naira tí wọn lo gba fun iyawo awọn aṣofin lati fi rin irinajo siluu Dubai.
O ni loootọ loun gba owo ọhun, ati pe miliọnu mẹrin mẹrin naira ni ẹni kọọkan awọn obinrin ọhun gba, ti wọn fi gun baaluu ati ounjẹ pẹlu inawo mi-in to waye lọhun-un.
O ni oun ko gba iru owo bẹẹ ri funra oun lati fi rin irinajo, ati pe iru irin ajo tawọn obinrin yẹn lọ a maa na eeyan lowo gidi, bẹẹ nitori ki awọn iyawo awọn le kẹ́kọ̀ọ́ tuntun lawon ṣe ṣe e. Loju ẹsẹ to sọ bẹẹ ni igbimọ to n ṣèwádìí ẹ ti tu u silẹ, bẹẹ lọrọ ọhun fa ariwo nla, ti ẹgbẹ ajafẹtọọ loriṣiiriṣii si sọ pe ko yẹ kì wọn tu u silẹ bẹẹ.

Leave a Reply