EFCC ti gbe Alice atọrẹkunrin ẹ to lu ileeṣẹ kan ni jibiti miliọnu mẹtadinlogun naira lo si kootu n’Ibadan

 Ọlawale Ajao, Ibadan

Obinrin oniṣowo kan, Alice Peace John, ati ololufẹ ẹ, Fadi Alloush, ti n kawọ pọnyin rojọ ni kootu bayii nitori ẹsun jibiti ti wọn fi kan wọn nile-ẹjọ giga ijọba ipinlẹ Ọyọ to wa laduugbo Ring Road, n’Ibadan.

Ajọ to n gbogun ti jibiti owo ati iwa magomago, iyẹn Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, ẹkun Ibadan, lo pe wọn lẹjọ, wọn ni wọn lu ileeṣẹ kan ni jibiti miliọnu mẹtadinlogun Naira ati ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (N17.5m).

Ileeṣẹ aladaani ilẹ yii kan to n gbero lati ra eedu lọ silẹ okeere fun tita leyi to jẹ obinrin ninu awọn olujẹjọ yii, Alice, ṣadehun lati ba ra eedu lagbegbe Oke-Ogun, nipinlẹ Ọyọ, ti ileeṣẹ naa si sanwo sinu aṣunwọn rẹ laarin ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2019, si ọjọ kẹtalelogun, oṣu kejila, ọdun naa.

Gẹgẹ bi Ọmọwe Ben Ubi ti i ṣe agbejọro ajọ EFCC ṣe fidi ẹ mulẹ niwaju Onidaajọ Bayo Taiwo ti i ṣe adajọ kootu naa l’Ọjọruu, Wesidee, to kọja, lẹyin ti obinrin naa raja ọhun tan lo lẹdi apo pọ pẹlu ololufẹ ẹ to n jẹ Fadi, ti wọn si ta ọja naa fun ileeṣẹ mi-in nilẹ okeere.

Obinrin oniṣowo yii ko ra ọja mi-in rọpo fawọn to bẹ ẹ leeedu, bẹẹ ni ko da miliọnu mẹtadinlogun aabọ ti wọn ti fi ranṣẹ si i pada, niṣe loun ati ọrẹkunrin rẹ n fowo olowo ṣararindin.

Amofin Ubi sọ siwaju pe iwa ti awọn olujẹjọ yii hu lodi si ofin ori ọrinlelọọọdunrun ati mẹwaa (390), abala kejidinlogoji ofin to ṣe iwa ọdaran leewọ nipinlẹ Ọyọ, o si la ijiya lọ.

Lẹyin ti wọn ti ka ẹsun naa si wọn leti, ṣugbọn ti wọn ti sọ pe awọn ko jẹbi, Onidaajọ Taiwo fọwọ si beeli ti agbẹjọro wọn, Amofin Ọlukunle Kamisi, beere fun ninu igbẹjọ to ti kọkọ waye ṣaaju.

Iwaju Onidaajọ Iyabọ Yerima ti ile-ẹjọ giga ijọba ipinlẹ Ọyọ lajọ EFCC ẹkun Ibadan ti kọkọ gbe awọn ololufẹ mejeeji yii lọ ko too di pe wọn gbe ẹjọ naa kuro nibẹ lọ siwaju Onidaajọ Taiwo to n gbọ ọ lọwọ bayii.

Adajọ naa ti sun igbẹjọ ọhun si Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹjọ, oṣu kẹwaa, ọdun 2020 yii.

O waa kilọ fawọn olujẹjọ lati yago fun iwa fífàkókò ṣofo. O ni bi wọn ba gbe igbesẹ tabi ṣe ohunkohun lati jẹ ki igbẹjọ naa falẹ pẹrẹn, oun yoo fagi le beeli ti ile-ẹjọ ti fun wọn tẹlẹ, ti oun yoo si binu sọ awọn mejeeji satimọle.

 

Leave a Reply