EFCC ti mu gomina Imo tẹlẹ, Rochas Okorocha, ju sakolo wọn

Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku, EFCC, ti mu gomina ipinlẹ Imo tẹlẹ, Rochas Okorocha ju sakolo wọn bayii.

Ọsan ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni wọn mu ọkunrin naa lọọfiisi rẹ niluu Abuja gẹgẹ bi Alukoro ajọ EFCC, Wilson Uwujare, ṣe sọ.

Titi di ba a ṣe n sọ yii, ko ti i sẹni to le sọ idi pataki ti wọn fi mu gomina tẹlẹ yii ti mọle.

Okorocha to n ṣoju awọn eeyan agbegbe Guusu ipinlẹ Imo nileegbimọ aṣofin agba bayii ni ede aiyede nla n lọ laarin oun ati Gomina ipinlẹ naa lọwọlọwọ, Hope Uzodinma.

O ti ṣe diẹ tawọn gomina mejeeji yii ti n fẹsun ọlọkan-o-jọkan kan ara wa. Wahala ija naa lo si mu ki ijọba ipinlẹ Imo wo awọn ile kan, to si tun gbẹsẹ le awọn otẹẹli ati dukia mi-in ti wọn lo jẹ ti gomina ipinlẹ Imo tẹlẹ naa ati iyawo rẹ.

Awọn kan ti n sọ pe wahala to ba gomina Imo tẹlẹ yii ko sẹyin gomina to wa nipo nipinlẹ naa bayii.

Leave a Reply