EFCC tun ri miliọnu lọna aadoje naira gba lọwọ awọn to ko owo ilu jẹ ni Kwara

Stephen Ajagbe, Ilọrin
Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ati ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu, EFCC, ẹka ti ipinlẹ Kwara ni awọn ti tun ri miliọnu lọna aadoje naira gba lọwọ awọn to ko owo ilu jẹ.
Ọga agba tuntun ajọ naa, Oseni Kazeem, lo sọrọ ọhun l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, nigba to ṣe abẹwo si Gomina Abdulrahman Abdulrazaq ni ọfiisi rẹ. Oseni ni laipẹ lawọn yoo fa owo naa le ijọba lọwọ.
Gomina Abdulrahman gboṣuba kare fun ajọ naa lori bo ṣe n gbogun ti iwa ibajẹ, to si n tọpinpin gbogbo awọn to ti ko owo ilu sapo ni Kwara.
O ni owo tajọ naa ti n gba pada lọwọ awọn jẹgudujẹra oloṣelu ti ran ipinlẹ Kwara lọwọ lati ni itẹsiwaju ju ti tẹlẹ lọ.
Gomina fi kun un pe lara igbesẹ ti EFCC gbe ni bi wọn ko ṣe jẹ ki biliọnu mẹrin aabọ naira tijọba apapọ kọkọ fi ranṣẹ si Kwara bọ sọwọ awọn to ṣejọba lọ, lasiko toun n mura lati gbajọba.
Kazeem to jẹ olori EFCC nipinlẹ Kwara, Kogi ati Ekiti gboriyin fun Gomina Abdulrazaq fun ipa to n ko lati mu eto iṣejọba sun mọ araalu.

Leave a Reply