EFCC tun ti sọ Fani-Kayọde sahaamọ wọn l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Minisita tẹlẹ feto igbokegbodo ọkọ ofurufu nilẹ wa, Oloye Fẹmi Fani-Kayọde, tun ti dero ahamọ ajọ EFCC.

Awọn ẹṣọ ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku (Economic and Financial Crimes Commission), ni wọn fi pampẹ ofin gbe Fani-Kayọde ni nnkan bii aago mejila ọsan ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lasiko to n jade kuro nile-ẹjọ giga apapọ to wa niluu Ikoyi, l’Erekuṣu Eko.

Afurasi ọdaran naa ti kọkọ duro niwaju adajọ nigba ti igbẹjọ waye lori ẹsun yiyiwee ati kiko owo ọba jẹ, eyi to n jẹjọ rẹ lọwọ.

Ṣugbọn igbẹjọ naa ko le tẹsiwaju, niṣe ni ile-ẹjọ sun igbẹjọ to kan siwaju si ọjọ kẹrinlelogun, oṣu ki-in-ni, ọdun 2022 to wọle de tan yii.

Bi Fani-Kayọde ṣe n lọ sidii ọkọ ayọkẹlẹ rẹ, awọn ẹṣọ EFCC da a duro, wọn si kọ jalẹ pe ko le lọ bẹẹ, ni wọn ba gan an lapa, wọn si mu un sinu ọkọ tiwọn, wọn gbe e lọ sẹka ọfiisi wọn to wa niluu Ikoyi.

Ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ to n ṣiṣẹ pẹlu EFCC, Ọgbẹni Shehu Shuaibu, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni ahamọ awọn ni afurasi ọdaran naa wa, ati pe awọn iṣẹ iwadii kan n lọ lọwọ, o si gbọdọ dahun awọn ibeere kan lọdọ wọn.

Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja yii lariwo gba atẹ ayelujara kan pe wọn ti mu ọkunrin ẹni ọdun mọkanlelaaadọta naa, ṣugbọn Fani-Kayọde pada fi fidio kan lede nirọlẹ ọjọ naa pe ko sẹni to mu oun, o ni otẹẹli kan loun wa l’Abuja toun ti n ṣe faaji ni toun.

Lọtẹ yii, o ti dero ahamọ EFCC.

Leave a Reply