EFCC ya wọ ile igbafẹ kan n’Ibadan, ọmọ ‘Yahoo’ mẹwaa ni wọn ri mu

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nnkan ko ṣẹnuure fawọn afurasi onijibiti kan ti wọn n pe lọmọ ‘Yahoo’ nigboro Ibadan lafẹmọju aarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ kọja pẹlu bi awọn oṣiṣẹ EFCC, iyẹn ajọ to n gbogun ti jibiti ati iwa magomago, ẹka tilu Ibadan ya lu wọn lojiji nibi ti wọn ti n ṣe faaji lọwọ.

O jọ pe iṣẹ ọwọ awọn paapaa ko fi wọn lọkan balẹ. Bi wọn ṣe ri awọn agbofinro ni wọn fọn danu, ti kaluku si wa’bi sa gba lọ. Ṣugbọn mẹwaa ninu wọn lọwọ awọn EFCC papa tẹ, ti wọn si fi ṣẹkẹṣẹkẹ ko wọn lọ sinu atimọle.

Orukọ wọn ni Isaac Ogundayọ; David Ayọdele; Etiowe Kelvin; Ṣeun Afọlabi; Saheed Ọlalekan; Oluwatobi Damilọla; Sukanmi Ọdọfin; Ademọla Okunọla; Joseph Damilare ati Abass Sodiq.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fawọn oniroyin n’Ibaban, Agbenusọ fun ajọ EFCC, Ọgbẹni Wilson Uwujaren sọ pe awọn to ri ọna ti awọn ọmọdekunrin wọnyi n gba nawo ninaakunaa ni wọn ta ajọ EFCC lolobo ti awọn fi lọọ ka wọn mọ ode faaji ti wọn ti n ba owo ninu jẹ lọwọ laduugbo Ajinde, nigboro Ibadan, nibi ti wọn ti ṣe ariya lati alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, mọju Furaidee.

ALAROYE gbọ pe oriṣiiriṣii ayederu iwe, eyi to jọ pe wọn fi lu awọn eeyan ni jibiti lawọn agbofinro ka mọ awọn afurasi ọmọ ‘Yahoo’ wọnyi lọwọ.

Ni kete ti iwadii ba pari lori iṣẹlẹ yii lajọ EFCC yoo gbe awọn mẹwẹẹwa lọ sile-ẹjọ gẹgẹ bi agbẹnusọ ajọ naa ṣe fidi ẹ mulẹ.

Leave a Reply