Jọkẹ Amọri
Ẹka to n mojuto iwa ọdaran to wa ni Yaba, niluu Eko, ni ileeṣẹ ọlọpaa gbe baale ile kan, Benedict Anieze, lọ latari bo ṣe wo sunsun, to si la ọmọ oṣu kan tiyawo rẹ ṣẹṣẹ bi mọlẹ, lẹyin eyi lo dana sun ile ti wọn n gbe, to si sa lọ.
Gẹgẹ bi akọroyin Punch ṣe ṣalaye, ni ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹta, oṣu Kẹrin yii, ni Benedict sadeede he ọmọbinrin naa nile wọn to wa ni adugbo Pipeline, Idimu, niluu Eko, to si sọ ọmọ naa mọlẹ bii igba teeyan ba fagbara ju okuta silẹ, bẹẹ lori ọmọ oṣu kan yii fọ yanga, to si ku loju-ẹsẹ.
O jọ pe lẹyin to huwa naa tan ni oju rẹ walẹ, to si n wa gbogbo ọna lati ri i pe aṣiri iwa ibi to hu naa ko han saraye. Eyi lo mu ko tun da ọran mọran pẹlu bo ṣe dana sun ile to n gbe, to si fi iyawo rẹ, Promise, ẹni ti wọn ni ko ju ọmọ ọdun mẹtadinlogun lọ, ati oku ọmọ naa silẹ nibẹ, to sa lọ.
Iyawo to wa ninu ile yii la gbọ pe o pe awọn araadugbo ki wọn waa ran oun lọwọ, iyalẹnu lo si jẹ fun wọn nigba ti wọn ba ọmọ naa nilẹẹlẹ to ti ku. Awọn eeyan yii ni wọn pa ina to n jo ninu ile ọhun gẹgẹ bi iweeroyin Punch ṣe ṣalaye.
Ibinu ọrọ yii lawọn araadugbo naa fi sin in lọ si teṣan ọlọpaa pe ko lọọ fẹjọ ọkunrin naa sun, bẹẹ lawọn mi-in ninu wọn tun kora wọn jọ, ti wọn n wa ọkunrin to ṣiṣẹ buruku naa kiri.
Awọn ọlọpaa pẹlu awọn araadugbo yii ni wọn pada ri ọkunrin naa nibi to farapamọ si, ti wọn si mu un lọ si teṣan ọlọpaa.
Nigba ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, n ṣalaye lori iṣẹlẹ naa, o ni ọkunrin naa ni ko si ija laarin iyawo oun to jẹ iya ọmọ naa, ṣugbọn ẹmi eṣu lo ba le oun ti oun fi gbe ọmọ naa, ti oun si sọ ọ mọlẹ to fi ku.
Ile igbokuusi to wa ni ọsibitu ijọba, ni Yaba, ni wọn gbe oku ọmọ naa lọ.
Bakan naa lawọn agbofinro ti taari ọkunrin naa si ẹka to n ri si iwa ọdaran nipinlẹ Eko to wa ni Yaba.