Jacob fipa ba ọmọ to bi lo pọ n’llọrin, lo ba ni iṣẹ eṣu ni

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Akolo ajọ ẹṣọ alaabo ṣifu difẹnsi, ni ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlaaadọta kan, Jacob Obomerelu, wa bayii to ti n ṣẹju pako, fun ẹsun pe o fipa ba ọmọ to bi ninu ara rẹ ti ko ju ọdun mejidinlogun lọ lo pọ.

Ninu atẹjade ti Agbẹnusọ ajọ ẹṣọ naa ni Kwara, Babawale Zaid Afolabi, fi sita ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, lo ti salaye pe ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, niṣẹlẹ naa waye nibi ti afurasi naa ti n ṣiṣẹ niluu Ilọrin, to si jẹ pe ibẹ naa lo n gbe.

O tẹsiwaju pe arabinrin ti ọmọ naa n gbe lọdọ rẹ tẹlẹ, Alaaja Mariam Bello, ṣalaye fun ajọ naa pe ọdọ oun ni ọmọdebinrin yii n gbe tẹlẹ ni agbegbe Gaa Akanbi Isalẹ, ṣugbọn nigba ti ede-aiyede kekere kan waye lo binu kuro lọdọ oun, to si lọ n gbe pẹlu baba rẹ nibi to ti n ṣiṣẹ. Alaaja Mariam ni lati ọdun 2017 ti Jacob ati iyawo rẹ ti pingaari ni ọmọ naa ti n gbe papọ pẹlu oun.

Nigba ti ọmọbinrin  ọhun n ba ẹsọ alaabo sọrọ, o ni ọjọ akọkọ ti oun ko lọ si ọdọ baba oun nibi ile to ti n ṣiẹẹ ọdẹ ni iṣẹlẹ buruku naa ti bẹrẹ. O loun bẹ baba pe ko maa dan an wo, ṣugbọn baba ko gba, niṣe lo n bẹbẹ pe oun yoo fun un ni ẹgbẹrun kan naira ti yoo fi ra oogun ti yoo fọ ọ danu lẹyin ti wọn laṣepọ tan.

Nigba tọwọ tẹ Jacob, o jẹwọ pe loootọ loun fipa ba ọmọ naa lo pọ, ṣugbọn iṣẹ eṣu ni. Adari agba ajọ ṣifu difẹnsi, Iskilu Ayinla Makinde, ti waa ni ki wọn ṣe ẹkunrẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa, ki wọn si gbe afurasi naa lọ si ile-ẹjọ lẹyin iwadii.

 

Leave a Reply