Ẹfun abeedi, lẹyin ti baale ile kan gba ipe tan lori foonu lo bẹ sodo Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ ni awọn ọlọpaa pẹlu awọn oṣiṣẹ panapana ṣi n wa ọkunrin kan to bẹ sinu odo Ọṣun nirọlẹ Ọjọruu,  Wẹsidee, ọsẹ yii.

Nnkan bii aago mẹrin kọja ogun iṣẹju la gbọ pe iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ lori biriiji Gbodofọn, to wa loju-ọna Gbọngan si Oṣogbo.

Ipe kan lọkunrin ti ẹnikẹni ko ti i da mọ naa gba lori foonu rẹ, lẹyin eyi lo ju foonu sinu odo, ko too di pe oun funra rẹ bẹ sinu odo ọhun.

Ọkada kan to ni nọmba PKA 915 VI lọkunrin naa wa de ori biriiji ko too gba ipe naa, gẹgẹ bi awọn tiṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn ṣe sọ.

Ọkunrin ọlọkada kan, Abidemi Adedire, ṣalaye pe ko sẹni to le fura pe ọkunrin yii le ṣe nnkan to ṣe, o ni ṣe lo n pariwo sọrọ nigba to n gba ipe naa, ṣugbọn ariwo awọn ọkọ to n kọja ko jẹ koun le feti si nnkan to n sọ.

O ni ko pa ina ọkada rẹ gan-an lasiko to n gba ipe naa, bo si ṣe sọrọ tan lo ju foonu sinu odo, ki awọn eeyan si too de ọdọ rẹ, o ti bẹ sodo Ọṣun.

Alakooso ajọ panapana l’Ọṣun, Ibrahim Adekunle, sọ pe oṣiṣẹ awọn kan to n kọja lọ lasiko iṣẹlẹ naa lo fi to awọn leti, kia lawọn si bẹrẹ igbesẹ lati wa a, ṣugbọn odo to kun bayii le fa idiwọ diẹ.

Bakan naa ni Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, fidi iṣẹlẹ.naa mulẹ, o ni awọn ti n gbe igbesẹ lati ṣawari ọkunrin naa.

Leave a Reply