Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọmọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlogun kan tórúkọ rẹ n jẹ Precious lo ti wa lakolo awọn ẹsọ Amọtẹkun ni olu Ileesẹ wọn to wa l’Akurẹ lori ẹsun fi fi ipa ba iyawo ẹgbọn rẹ àtàwọn obinrin mẹsan-an mi-in lo pọ l’Ondo.
Gẹgẹ bi alaye ti adari ẹsọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Akọgun Adetunji Adelẹyẹ ṣe fun wa, iṣẹlẹ yii lo ni ó waye ninu abule kan ti wọn n pe ni Laoso n’ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo.
Precious yii ni wọn lọwọ awọn agbofinro tẹ lẹyin toun nikan lọọ ji kẹẹgi epo pupa bíi mẹẹdọgbọn nigba to ṣakiyesi pe ẹgbọn oun ko si nitosi, bakan naa lo tun lo anfaani asiko naa lati fi ba iyawo ẹgbọn rẹ lo pọ ni tipátipá.
Adelẹyẹ ni ọdọmọdekunrin ọhun fẹnu ara rẹ jẹwọ fun awọn nigba ti awọn ń fọrọ wa a lẹnu wo pe lóòótọ́ loun ji epo pupa naa lati fi owo rẹ ra foonu olowo nla kan.
Afurasi ọhun ni ihooho ọmọluabi ti oun ba iyawo ẹgbọn oun nibi to sun si lori bẹẹdi ninu yara ọkọ rẹ nigba toun fẹẹ lọọ jale lo ko si òun lori ti oun fi fipa ba Abilekọ naa sun.
Awọn obinrin mẹsan-an mi-in tọjọ ori wọn wa laarin ọdun mọkandinlogun si mẹẹdọgbọn lo ni oun tun tí fipa ba sun labule naa lọwọ too pada tẹ ẹ.
Adelẹyẹ ni awọn ti n ṣeto ati wọ ọmọkùnrin naa lọ s’ile-ẹjọ lẹyin ti iwadii ba ti pari lori ẹsun ti wọn fi kan an.