Ẹgbẹ Afẹmiṣofo ni Miyetti Allah, ẹ tete kede wọn bẹẹ – Awọn ajijagbara

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ẹbẹ ti apapọ ẹgbẹ ajijagba ilẹ Yoruba n bẹ ajọ agbaye, (United Nation) bayii ni pe ki wọn tete kede ẹgbe awọn Fulani darandaran, Miyetti Allah, gẹgẹ bii ẹgbẹ afẹmiṣofo ni Naijiria. Wọn ni nitori awọn eeyan naa ki i ṣe darandaran lasan, iranṣẹ iku latọdọ awọn ISIS atawọn ẹgbẹ buruku afẹmiṣofo kaakiri agbaye ni wọn.

Ninu atẹjade kan ti apapọ ẹgbẹ to n beere idasilẹ Orilẹ-ede Yoruba ati awọn ẹya mi-in naa ti wọn fẹẹ da duro kọ si Ajọ Agbaye ni ọrọ yii ti jade. Alaga awọn ẹgbẹ yii, Baba agba, Ọjọgbọn Banji Akintoye, lo ṣagbatẹru rẹ.

Wọn kọ atẹjade ọhun si Ajọ Agbaye ṣaaju iwọde agbayanu ti wọn ti kede rẹ pe yoo waye niluu oyinbo, iyẹn lọjọ kẹrinla, oṣu kẹsan-an yii, titi di ọjọ kẹrinlelogun, oṣu yii.

“ Ijọba lo n ṣagbatẹru ifẹmiṣofo ni Naijiria lasiko yii, bẹẹ ni awọn darandaran asiko yii yatọ sawọn alarinkiri Fulani ta a gbọnju ba. Awọn tasiko yii n paayan kiri ni. Iranṣẹ awọn ẹgbẹ afẹmiṣofo bii ISIS,AL-QUAEDA, ISWAP ati Boko-Haram ni wọn. wọn fi wọn ṣọwọ si Naijiria latọhun-un pe ki wọn maa waa da wahala silẹ ni.

“A fẹ ki opin de ba ipaniyan to n ṣẹlẹ nipasẹ ẹlẹyamẹya, ati bi wọn ṣe n pa awọn eeyan nitori ẹsin ti wọn n ṣe ni Naijiria. Pẹlu ogo Ọlọrun, bi a ba de ibi iwọde yii, a maa ni ki awọn olori kaakiri agbaye, kede Miyetti Allah bii ẹgbẹ afẹmiṣofo.

“Ohun to lewu ni lati pe ẹgbẹ Miyetti Allah lẹgbẹ oniṣowo lasan, ẹgbẹ to lewu fun aabo Guusu ilẹ Naijiria ati ti ẹya Middile Belt ni. Ẹgbẹ afẹmiṣofo ti ijọba Naijiria asiko yii n tilẹyin ni, nitori wọn fẹẹ gbe Fulani bori gbogbo ẹya to ku, ki Fulani le maa ṣe olori fun gbogbo wọn.”

Bẹẹ ni apa kan atẹjade awọn ajijagba Yoruba naa wi.

Wọn waa fi kun un pe ofin ti Naijiria n lo lọwọ, eyi ti wọn ṣe lọdun 1999 gbọdọ di nnkan igbagbe ko too di 2023 ti ibo yoo waye, nitori ofin jibiti paraku ni, ofin to role apa kan to da apa kan si ni.

Wọn ni gbogbo awọn eeyan tijọba n fi Fulani da laamu ti sun kan ogiri wayi, wọn lawọn ko fẹ ijẹgaba-le-ni lori nilẹ ẹni mọ, ki Ajọ Agbaye foju agba wo ohun to n ṣẹlẹ ni Naijiria ninu ipade ẹlẹẹkẹrindinlọgọrin ti wọn fẹẹ ṣe yii, iyẹn 76th United Nations General Assembly, kawọn eeyan Naijiria le yan ohun ti wọn fẹ funra wọn.

 

Leave a Reply