Ẹgbẹ akẹkọọ ṣe iwọde nitori apaayan to sa lọ lagọọ ọlọpaa n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nnkan ko fara rọ lolu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Ẹlẹyẹle, niluu Ibadan, ni Wẹsidee, ọsẹ yii, pẹlu bi ẹgbẹ awọn akẹkọọ ni Naijiria (NANS), ẹka ti ipinlẹ Ọyọ, ṣe tu jade, ti wọn si n fi ẹhonu han lodi si bi awọn ọlọpaa ṣe ni ọmọkunrin to n paayan l’Akinyẹle, Sunday Shodipẹ, dawati lagọọ wọn.

Wọọrọwọ ni wọn kọkọ bẹrẹ iwọde naa, ṣugbọn ko pẹ rara ti awọn akẹkọọ ọhun fi bẹrẹ si i ju okuta ati oriṣiiriṣii nnkan mi-in lu awọn ọlọpaa, ti wọn si n pariwo pe afi ki wọn wa ọdaran naa jade kiakia. Pẹlu bi wọn ṣe n ṣe yii, awọn agbofinro naa ko ba wọn fa wahala rara, niṣe ni wọn n wo wọn.

Nigba ti wọn n ba Kọmiṣanna awọn ọlọpaa, Nwachukwu Enwonwu, sọrọ, wọn fi aidunnu wọn han si iṣẹlẹ naa, wọn si ni ki ọkunrin naa ri i pe awọn ọmọọṣẹ rẹ ṣawari ọdaran to sa lọ naa.

Nigba to n ba wọn sọrọ, ọga ọlọpaa naa ni gbogbo agbara to wa ni ikapa awọn lawọn maa sa lati ri i pe ọdaran naa di riri.

Niṣe ni sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ gba gbogbo agbegbe naa pẹlu bi awọn akẹkọọ ọhun ṣe rọ di oju ọna, eyi to di lilọ bibọ ọkọ lọwọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Olugbenga Fadeyi fidi iṣẹlẹ naa mulẹ. O ni loootọ ni ẹgbẹ awọn akẹkọọ waa fẹhonu han lori ọdaran to sa lọ lagọọ awọn, ọga ọlọpaa atawọn alaṣẹ to ku si jade si wọn lati teti bẹlẹjẹ gbọ ẹdun ọkan wọn.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lawọn agbofinro kede pe awọn n wa ọdaran naa, wọn ni o sa lọ nibi tawọn fi i pamọ si.

Leave a Reply