Stephen Ajagbe, Ilorin
Fọfọ ni gbọngan aṣa ati iṣe-ọna, Kwara State Arts Council, to wa ni Geri Alimi, niluu Ilọrin, kun pẹlu awọn ọmọwe nipa ede ati aṣa Yoruba atawọn olukọ agba nipinlẹ Kwara, nibi ayẹyẹ ọdun aṣa ati ifami-ẹyẹ da ni lọla ti ẹgbẹ akẹkọọ ijinlẹ ede Yoruba ilẹ Naijiria ṣe lọsẹ yii.
Agba-ọjẹ to mọ nipa igbelarugẹ aṣa ati ede Yoruba nni, Ọgbẹni Bisi Oyewọle, lo jẹ olugbalejo ayẹyẹ naa.
Oriṣiiriṣii afihan aṣa, bii ijo jijo, iwọṣọ, ewi kike, orin kikọ, ere oniṣe ati bẹẹ lọ, lawọn akẹkọọ ede Yoruba kaakiri awọn ileewe giga to wa nipinlẹ Kwara fi dabira nibẹ.
Awọn ileewe to ko aṣoju wa sibẹ ni; Fasiti ilu Ilọrin, Fasiti ipinlẹ Kwara, KWASU, ileewe olukọni, tilu Ilọrin, ileewe olukọni tilu Oro ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Akori idanilẹkọọ to waye nibẹ ni; Ọsẹ́ ti ẹsin ajoji ati ọlaju ṣe fun aṣa Yoruba’. Ọmọwe Adeyẹmọ Olufẹmi Gabriel to jẹ olori ẹka ede Yoruba ni ile-ẹkọ olukọni agba ipinlẹ Ọṣun (Ila Ọrangun) lo ṣedanilẹkọọ naa.
Lara awọn alejo pataki ọjọ naa ni; Alhaji Abdulfatai Adeniyi Dan-Kazeem to jẹ alakooso fun ọrọ itaniji araalu nipinlẹ Kwara, Ọga agba ileewe girama Queens School, Alhaja Sidikat Taiye Lawal, Alaga awọn ọga ileewe girama (ANCOPSS) ti Zone 3, Alhaja Funmilayọ Abdulrahman, Alhaji Bakare Laarọ Ayinla, Mallam Saka Ahmed to jẹ akọwe ẹka eto ẹkọ lẹkun Gusu Ilọrin, Ọga agba ileeṣẹ redio Harmony FM, to wa niluu Idọfian, nipinlẹ Kwara. Bẹẹ lawọn ọga agba ileewe girama tun wa nibẹ.
Nibi ayẹyẹ ọhun ni wọn ti fi ami-ẹyẹ da awọn eeyan kan lọla fun akitiyan wọn lori idagbasoke ẹkọ ede abinibi. Lara wọn ni; Abilekọ Harriet Afọlabi Ọṣhatimẹhin (Iya Aṣa Ẹgbẹ), Oloye Mobọlaji Ajakitipa (Ọba Etutu Agbaye), Alhaji Toyin Abdullahi to jẹ Aarẹ ANCOPSS ẹka Kwara, Alhaja Muritala Sherifat, Ọga agba ileewe JSS Al-Adabiyah Kamaliyah, to wa niluu Ilọrin ati Oloye Saliu Babatunde Bakare (Aniyikaye Aṣa Yoruba).
Nigba to n sọrọ lorukọ gbogbo awọn to gbami-ẹyẹ naa, Alhaji Toyin Abdullahi dupẹ lọwọ ẹgbẹ akẹkọọ ijinlẹ Yoruba fun mimọ riri iṣẹ ribiribi tawọn ti ṣe, eyi to mu ki ami-ẹyẹ naa waye.
Ninu ọrọ idupẹ lati ẹnu Alhaji Abdulmualiy Adegboyega, Ọga agba ileeṣẹ redio Harmony FM, Idọfian, o ni inu oun dun pupọ fun awọn ti wọn gba ami-ẹyẹ ni ọjọ naa. O ni ki i ṣe pe wọn fun wọn nitori owo tabi ojuṣaaju, bi ko ṣe nitori akitiyan wọn.