Ẹgbẹ alatako ni oṣelu ni Akeredolu fẹẹ fi owo ileewe fasiti to din ku l’Ondo ṣe

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Oriṣiiriṣii ọrọ lawọn ẹgbẹ alatako n sọ si Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, lori bo ṣe kede adinku si owo ileewe ti wọn n san ni Fasiti Adekunle Ajasin to wa l’Akungba-Akoko.

Ko ju bii ọdun kan pere ti wọn dibo yan gomina ọhun lo kede afikun owo ile-iwe ti wọn n san ni fasiti naa lati ẹgbẹrun marundinlogoji naira si ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira, nigba towo awọn akẹkọọ to n kọ nipa imọ ofin ko din lẹgbẹrun lọna igba naira.

Lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ ati ariwo nijọba too gba lati yọ diẹ kuro lara awọn owo naa, owo ileewe ti wọn si n san lati igba naa wa laarin ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un si ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira.

Gbogbo igbiyanju awọn ẹgbẹ akẹkọọ ipinlẹ Ondo lati ba gomina sọrọ lori ọrọ owo ileewe tuntun ọhun lati bii ọdun meji sẹyin ko seso rere.

Iyalẹnu lo jẹ fawọn araalu l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, nigba ti wọn gbọ pe ijọba tun ti ge owo tawọn ọmọ ile-iwe ọhun n san sẹyin, ijọba ni  nitori ọrọ arun Korona to wa nita lawọn fi ṣe bẹẹ.

Ni ibamu pẹlu ikede tuntun yii, ẹgbẹrun lọna ọgọrin naira lawọn akẹkọọ to n kọ nipa eto-ẹkọ ati iṣẹ-ọwọ yoo ma san dipo ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un ti wọn n san tẹlẹ.

Dipo ẹgbẹrun lọna aadọjọ tawọn to wa lẹka ti wọn ti n kọ nipa imọ-sayẹnsi, eto-ọgbin ati imọ-iṣakoṣo n san, owo ọhun ni wọn ti din ku si ẹgbẹrun lọna ọgọfa naira pere. Ẹgbẹrun lọna aadọjọ ni tawọn to n kẹkọọ nipa imọ-ofin dipo ẹgbẹrun lọna ọgọsan-an ti wọn n san tẹlẹ.

Igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo, Ọnarebu Agboọla Ajayi,  lo kọkọ fa ibinu yọ lẹyin ikede naa, to si bu ẹnu atẹ lu bo ṣe jẹ pe asiko yii ni iru igbesẹ bẹẹ ṣẹṣẹ n waye. Ajayi ni iwa ẹtan patapata ni bi Akeredolu ṣe n mu adinku ba owo ileewe yii lẹyin ti ọpọ awọn akẹkọọ ti kuro nileewe latari airowo san.

O ni ọrọ owo ile-iwe ti wọn ṣe afikun rẹ lojiji yii wa lara ohun to da ija silẹ laarin oun ati gomina lati bii ọdun diẹ sẹyin.

Ọnarebu yii ni Arakunrin kan fẹẹ fi ikede naa tan awọn eeyan jẹ ni, ki i ṣe tori ifẹ to ni si wọn lo ṣe n din owo ile-iwe ku nigba ti eto idibo ku bii oṣu kan ati ọṣẹ meji pere.

Alukoro ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ondo, Kennedy Ikantu Peretei, ni ohun to pa ni lẹrin-in ni bo ṣe jẹ asiko yii gan-an lọkunrin ara Ọwọ naa ṣẹṣẹ ri i pe o tọ lati gbọ ẹbẹ tawọn obi ati ẹgbẹ akẹkọọ ti n bẹ ẹ lati bii ọdun meji sẹyin.

O ni ko si bi Akeredolu ṣe le gbọn to ti ko ni i fidi-rẹmi ninu eto idibo to n bọ lọna nitori pe oju awọn eeyan ti la, bẹẹ ni wọn ko ni i fẹẹ wọnu ajaga gomina ọhun fun ọdun mẹrin mi-in.

 

Leave a Reply