Ile-ẹjo ko le fofin de Abiru l’Ekoo, APC lo sọ bẹẹ

Jide Alabi

Ẹgbẹ oṣelu APC, ti ni ki ile-ẹjọ da ẹjọ ti ẹgbẹ oṣelu PDP pe pe Ọgbẹni Tokunbọ Abiru ko lẹtọọ lati dije dupo sile-igbimọ aṣofin agba, lati lọọ ṣoju agbegbe Ila-Oorun Eko, niluu Abuja.

Ile-ẹjọ giga kan l’Ekoo, nibi ti ẹgbẹ oṣelu PDP pẹjọ ọhun si ni APC naa ti rọ adajo ko tete da ẹjọ ọhun nu nitori ti ko lẹsẹ nilẹ rara.

Ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹfa, ọdun 2020 yii, ni arun koronafairọọsi pa Sẹnetọ Bayọ Oṣinọwọ tawọn eeyan tun mọ si Peperito, ẹni ti i ṣe aṣofin to n ṣoju agbegbe naa niluu Abuja. Oludije ẹgbẹ oṣelu PDP sileegbimọ aṣofin yii, Babatunde Gbadamọsi, lo gbe ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC yii lọ sile-ẹjọ, o ni ki ile-ẹjọ paṣẹ pe ko lẹtọọ lati dupo ọhun.

Ẹsun ti Gbadamọsi ka si Abiru lẹsẹ ni pe kaadi idibo meji ọtọotọ loun nikan ni, bẹẹ leyi ko tọna labẹ ofin.

Bakan naa lo tun sọ pe ọkunrin to n gbegba lati lọọ ṣoju awọn eeyan Ila-Oorun ipinlẹ Eko yii ko forukọ silẹ lagbegbe naa gẹgẹ bii oludibo.

Nigba ti igbẹjọ na waye, alaye ti agbẹjọro fun Abiru, Ọgbẹni Kẹmi Pinheiro, ṣe ni pe ki Adajọ Chuka Obiozor da ẹjọ naa nu, nitori ko lẹsẹ nilẹ rara, ati pe ọrọ to ti kọja lọ lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP fẹẹ maa pọn gegẹ.

O fi kun un pe gẹgẹ bi ofin Naijiria ṣe la a kalẹ, ti ẹnikẹni ba ni ẹjọ tabi akiyesi lori ibo to fẹẹ waye, irufẹ ẹjọ tabi akiyesi ọhun ti gbọdọ waye lati nnkan bii ọsẹ meji ki eto idibo too waye.

Pinheiro sọ pe ohun ti wọn pe ẹjọ le lori yii ti ṣẹlẹ saaju ọjọ kẹrinla, oṣu kẹsan-an, bẹẹ ni alaafo ọjọ mẹrinla ṣi wa ṣaaju ki igbẹjọ too waye.

O ni bi igbẹjọ ko ṣe waye laarin ọjọ mẹrinla ọhun ti sọ ẹjọ naa di obu mọ wọn lọwọ.

Agbẹjọro fun ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọgbẹni Ẹbun Ọnagoruwa, ti tọrọ aaye nile-ẹjọ lati wo awọn iwe ti agbẹjọro ẹgbẹ oṣelu APC fi ta ko ẹjọ naa, bẹẹ ni Adajọ Obiozor ti sun igbẹjọ mi-in lori ọrọ ọhun si ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹsan-an, ọdun yii.

 

Leave a Reply