Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ-binrin Eko fẹhonu han lori iwa ifipabanilopọ

Faith Adebọla

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ-binrin lorileede yii, ẹka ti Eko (Trade Union Congress Women Commission, Lagos State) ṣe iwọde wọọrọwọ lonii, Ọjọbọ, Tọsidee, ta ko iwa ifipabanilopọ ti wọn lo ti di lemọlemọ nipinlẹ Eko ati kari orileede Naijiria.

Oriṣiiriṣii akọle ni wọn gbe dani wa sileegbimọ aṣofin Eko, nibi ti aṣofin Ọnarebu Victor Oluṣẹgun Akande, Ọnarebu Ọlayiwọla Ọlawale ati Ọnarebu Nureni Akinsanya ti tẹti si aroye wọn lorukọ olori wọn, Ọnarebu Mudaṣiru Ọbasa.

Alaga ẹgbẹ naa, Abilekọ Oyejide, ṣalaye pe bo tilẹ jẹ pe ofin ti wa nilẹ to ta ko iwa buruku ọhun, sibẹ, awọn fẹ kawọn aṣofin tubọ ro ofin ọhun lagbara debi ti yoo ti ṣoro fẹnikẹni to bu huwa ifipa ba ni lo pọ lati jajabọ, ki igbẹjọ ati idajọ ẹsun ifipa ba ni lo pọ maa tete waye, ki akọsilẹ awọn to ba lọwọ ninu iwa naa lati ipinlẹ kan si omi-in wa larọọwọto debii pe yoo ṣoro fẹni to huwa aidaa naa nipinlẹ kan lati lọọ fori pamọ sipinlẹ mi-in.

Lara akọle tawọn olufẹhonu han naa gbe dani ni: “Ẹ yee ṣe awa obinrin baṣubaṣu,” “Obinrin ki i ṣe nnkan iṣere ọmọde,” “O to gẹẹ! Ifipa ba ni lo pọ to gẹẹ”.

Aṣofin Akande to jẹ alaga igbimọ alabẹ-ṣekele lori eto idajọ, ẹtọ ọmọniyan ati ẹsun to kan araalu gboriyin fun iwa akin ati ọna jẹẹjẹ ti wọn fi ṣe iwọde wọn, o ni awọn atunṣẹ kan ti n lọ lọwọ lori ofin to kan iwa ifipa ba ni lo pọ nipinlẹ Eko. Obinrin yii ṣalaye pe awọn aṣofin yoo ṣagbeyẹwo lẹta wọn, wọn yoo si wo bi wọn ṣe le kọ awọn ibeere ati ẹdun ọkan wọn mọ abadofin ti wọn n siṣẹ lori lọwọ, ati pe awọn yoo tubọ jara mọṣẹ lori ati mu ofin naa wa soju taye laipẹ.

CATIONS (Awọn fidio ati fọto)

Leave a Reply