Ẹgbẹ awọn onimaaluu rọ awọn aṣofin lati kọyin si abadofin fifi maaluu jẹko ni gbangba

Faith Adebọla

Latari bawọn gomina ilẹ Yoruba ati iha Guusu ilẹ wa ṣe gun le bibuwọ lu ofin ta ko fifi maaluu jẹko ni gbangba kaakiri awọn agbegbe nipinlẹ kaluku, ẹgbẹ awọn onimaaluu ilẹ Hausa, Miyetti Allah Kautal Hore, ti parọwa sawọn aṣofin apapọ nilẹ wa pe ki wọn gbegi dina fun awọn gomina ti wọn wa nidii ofin ọhun.

Akọwe apapọ fun ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Saleh Alhassan, lo rawọ ẹbẹ yii lorukọ ẹgbẹ wọn nibi ayẹyẹ kan ti wọn fi yan Abilekọ Amina Temitọpẹ Ajayi gẹgẹ bii Aṣoju ẹgbẹ, eyi to waye niluu Uke, nipinlẹ Nassarawa.

Alhassan ni niṣe lawọn gomina ti wọn faake kọri pe dandan ni kawọn ṣofin ta ko fifi maaluu jẹko ni gbangba mọ-ọn-mọ fẹẹ finra ni, o lawọn Fulani darandaran ni wọn fẹẹ fofin naa da lọwọ kọ lẹnu okoowo wọn.

O ni ti wọn ba fi gba awọn gomina naa laaye lati jẹ ki ofin yii fidi mulẹ, wahala ati ija nla lo maa bi, o si le yọri si pipadanu awọn dukia ati awọn nnkan ọsin, eyi yoo si tun da ọpọ eeyan pada si ẹsẹ aarọ, tabi ki wọn di otoṣi paraku.

O ni ofin ti wọn fi ṣedasilẹ papa ijẹko kaakiri orileede yii ti wa tẹlẹ, ofin yii ni ki wọn ba awọn hu jade gẹgẹ bii Aarẹ Buhari ṣe paṣẹ laipẹ yii.

O tun rọ awọn aṣofin lati ṣagbeyẹwo ofin ilẹ, ki wọn si ṣatunṣe si i lawọn ibi to ba yẹ, tori ofin naa gbọdọ fawọn darandaran lanfaani lati bojuto awọn ẹran wọn ni gbogbo agbegbe Naijiria yii.

Bakan naa lọkunrin yii bẹnu atẹ lu Gomina ipinlẹ Benue, Samuel Orhom, fun bo ṣe taku lori ọrọ awọn darandaran, to si tun n sọrọ ṣakaṣaka si wọn lai wẹyin wo.

Leave a Reply