Jọkẹ Amọri
Ni igbaradi fun eto idibo ọdun 2023, ẹgbẹ awọn oniṣowo kan, (Businessmen for Ọṣinbajo), ti wọn n ṣatilẹyin fun Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Yẹmi Ọṣinbajo lati dije dupo aarẹ, ti sọ pe awọn ti ṣetan lati dawo jọ, tawọn yoo si gba fọọmu ti ọkunrin naa yoo fi dije dupo aarẹ lọdun to n bọ.
L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, ni wọn sọrọ naa nigba ti wọn n ṣe ifilọlẹ ẹgbẹ yii niluu Abuja. Awọn to n ṣe kokaari ẹgbẹ ti wọn lo jẹ ti awọn oniṣowo nla ati oniṣowo kereje kereje, to fi mọ awọn ti wọn nifẹẹ ẹgbẹ naa, ti wọn si finu fẹdọ darapọ mọ ọn kaakiri ipinlẹ mẹrẹẹrindinlogoji to wa nilẹ wa, Tayo Fagbohun ati Ọlatunji Davies, sọ pe Igbakeji Aarẹ wa ti n fi gbogbo igba ṣatilẹyin fun awọn oniṣowo pẹlu awọn ilana to le ran ọrọ aje wa lọwọ lorileede yii.
Fagbohun ni bo tilẹ jẹ pe Ọṣinbajo ko ti i bọ sita lati sọ pe oun fẹẹ dupo aarẹ ilẹ wa, nitori o n duro de ajọ eleto idibo lati kede asiko to yẹ, nitori gẹgẹ bii ẹni to mọ ofin, Ọṣinbajo ko fẹẹ ru ofin.
O ni pẹlu bi ko ṣe ti i kede erongba rẹ yii naa, sibẹ, awọn n ṣiṣẹ takuntakun lati ri i pe o di aarẹ ilẹ Naijiria nitori ọgbọn ori, imọ nipa ọrọ aje nilẹ yii ati bi gbogbo nnkan ṣe n lọ nipa ọrọ-aje lagbaaye ti Ọjọgbọn Ọinbajo ni.
Fagbohun ni, ‘‘Mo duro siwaju yin lonii lati ki yin kaabọ sinu irinajo lati gbe Naijiria ga. Igbega yii yoo si waye nigba ti awa ti a jẹ oniṣowo ba gba lati darapọ mọ iṣejọba awa-ara-wa ni Naijiria. Nitori pe a ko kọra si awọn nnkan yii tẹlẹ n mu ifasẹyin ba agbara ti a ni lori ọna ti a le gba lati mu irọrun ba okoowo ṣiṣe.
‘‘A ṣe idasilẹ ẹgbẹ ti a pe ni Business Men for Ọṣinbajo gẹgẹ bii igbesẹ akọkọ lati mu ayipada to yẹ wa. Ẹgbẹ yii jẹ awọn ti wọn fara wọn silẹ kaakiri ẹka ileeṣẹ okoowo kekere ati nla kaakiri awọn ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa nilẹ wa, to fi mọ olu ilu ilẹ wa ni Abuja. Ojuṣe wa naa si ni lati ri i pe Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, di aarẹ Naijiria lọdun 2023.’’
O fi kun un pe gbogbo ọna ni Ọṣinbajo ti ṣe afihan ifẹ si ọrọ aje wa ati lati mu ki ọrọ aje wa gberu, ko si gbooro si i pẹlu awọn eto oriṣiiriṣii bii jijẹ adari ti ko lẹlẹgbẹ, ṣiṣe amojuto ọrọ aje wa. Fun idi eyi atawọn ti mi-in ti a ko le maa ka, a ti pinnu lati gba fọọmu ti yooo fi dije fun un, gbogbo ara la si fi n ṣiṣẹ lati ri i pe o di aarẹ ilẹ wa lọdun to n bọ.
Fagbohun ni gbogbo ohun ti eeyan nilo lati dari orileede lo pe sara Ọṣinbajo lati le tẹsiwaju nibi ti Buhari ba pari rẹ si.
‘‘A ko fẹ ẹni ti yoo kan waa maa ṣe eyi jẹ eyi o jẹ, Ọṣinbajo wa nibẹ, o si jẹ ọkan lara awọn ti wọn ti jọ n ṣejọba yii. O mọ ibi ti nnkan ku si ati ohun ti o yẹ ko ṣe. Ki eleyii maa tẹsiwaju lo daa, ki gbogbo rẹ le fẹnu mura wọn.
‘‘Ki i ṣe pe a n sọ fun un pe ko dije nikan, a maa gba fọọmu idije fun un, awa naa si maa kopa ninu ilakaka rẹ lati di aarẹ, nitori oun nikan ni ẹni naa ti o ni ibaṣepọ to tọ laarin awọn ẹya lorileede wa ati lagbo oṣelu pẹlu ọrọ ẹsin.’’ Bẹẹ ni wọn pari ọrọ wọn.