Ẹgbẹ Emere Onitẹsiwaju ṣajọdun wọn l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Fọọfọọ ni tẹmpili Ọgbẹyọnu to wa ninu ile Araba Awo tiluu Oṣogbo, Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn, kun l’Ọjọbọ Tọsidee, ọsẹ yii, lasiko ti awọn ẹgbẹ emere onitẹsiwaju ṣayẹyẹ ajọdun ọdun keji idasilẹ ẹgbẹ wọn.

Kaakiri ijọba ibilẹ to wa nipinlẹ Ọṣun ni awọn ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ ti pe jọ sibi ọdun naa pẹlu aṣọ leesi funfun lọrun wọn.

Araba Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn ati Oloye Atanda Ifagbenuṣọla to jẹ Aṣiwaju Awo Agbaye naa ko gbẹyin nibẹ nitori awọn mejeeji ni babaasalẹ ẹgbẹ ọhun.

Ninu ọrọ apilẹkọ rẹ, Aarẹ ẹgbẹ Emere onitẹsiwaju kaakiri agbaye, Iyaooṣa Oyelọla Ẹgbẹyẹmi Ẹlẹbuibọn dupẹ lọwọ Eledumare fun anfaani to fun wọn lati ṣe ayẹyẹ naa, o si tun dupẹ lọwọ gbogbo awọn ti wọn jẹ oniṣẹse atawọn adari wọn kaakiri.

Iyaooṣa ṣalaye pe imugbooro aṣa ati ẹsin Yoruba lo ṣokunfa bi ọpọlọpọ wọn ṣe wa nibi ayẹyẹ ọhun. O ni awọn alalẹ (ancestors) ti fi ipilẹ iṣerere lelẹ fun aṣa Yoruba, o waa ku si iran yii lọwọ lati ma ṣe jẹ ko dohun igbagbe, ki laalaa awọn akọni Yoruba ma si ja sasan.

O fi kun ọrọ rẹ pe awọn eeyan orileede Europe, Amẹrika ati Latin ti n kọ asa ati ẹsin Yoruba, bẹẹ ni wọn n gbin in si ọkan awọn ọmọ wọn, ti wọn si n sọ ọ lai tiju, o waa ku si awa oni nnkan lọwọ bi ko ṣe ni i jẹ pe awọn eeyan orileede yẹn ni wọn yoo pada maa kọ awọn ọmọ wa.

Leave a Reply