Ẹgbẹ nọọsi fun ijọba Kwara ni ọjọ mẹẹẹdogun lati dahun si ibeere wọn

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ẹgbẹ awọn nọọsi ati agbẹbi nilẹ yii, ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti fun ijọba ni gbedeke ọjọ mẹẹẹdogun lati dahun si awọn ibeere lori ohun to ni i ṣe pẹlu irọrun awọn ọmọ ẹgbẹ ọhun tabi ki ẹgbẹ naa si gun le iyanṣẹlodi alaini gbendeke.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, ni ẹgbẹ naa ṣekilọ ọhun fun ijọba Kwara ninu atẹjade kan ti alaga wọn, Ọgbẹni Aminu Shehu, ati akọwe ẹgbẹ naa, Markus Luka, jumọ buwọ lu lẹyin ipade pajawiri kan ti wọn ṣe ni olu ile ẹgbẹ ọhun to wa niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara. Ẹgbẹ yii sọ pe awọn gbe igbeṣẹ yii lati ṣekilọ fun ijọba lori ọwọ ti wọn fi mu irọrun ati igbaye-gbadun awọn nọọsi ati agbẹbi lawọn ileewosan gbogbo nipinlẹ naa bii igbega lẹnu iṣẹ, eto aabo, awọn oṣiṣẹ ti ko to nnkan ati bẹẹ bẹẹ lọ, ti gbogbo awọn nnkan yii si n jẹ iṣoro fun awọn ọmọ ẹgbẹ naa.

Ẹgbẹ ọhun fẹsun kan ijọba pe o mọ-ọn-mọ pa ẹgbẹ naa ti bii aṣọ to gbo ni, ti wọn ba si kọ lati dahun si gbogbo ibeere yii lẹyin ọjọ mẹẹẹdogun, awọn yoo gun le iyanṣẹlodi ti ko ni gbedeke.

Leave a Reply