Ẹgbẹ oṣelu mọkanla ṣatilẹyin fun Jẹgẹdẹ, wọn loun lawọn yoo dibo fun

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ninu awọn ẹgbẹ oṣelu mẹtadinlogun to forukọ silẹ lati kopa ninu eto idibo ipinlẹ Ondo, mọkanla ninu wọn ti gba lati ṣiṣẹ pọ pẹlu Eyitayọ Jẹgẹdẹ to jẹ oludije ti ẹgbẹ PDP fa kalẹ ninu eto idibo to n bọ lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii.

Alaga ẹgbẹ SDP nipinlẹ Ondo, Ọmọọba Ọladele Ogunbamẹru, to gba ẹnu awọn ẹgbẹ yooku sọrọ ni awọn pinnu ati ṣatilẹyin fun Jẹgẹdẹ ki awọn eeyan ipinlẹ Ondo le jẹ anfaani ijọba tiwa-n-tiwa.

O ni oun to jẹ awọn logun ju lọ ni bi iṣejọba rere yoo ṣe fẹsẹ mulẹ ninu eto oṣelu ipinlẹ Ondo, nitori pe aṣiṣe patapata nijọba ẹgbẹ APC to n ṣakoso lọwọ jẹ fawọn eeyan.

Ọmọọba Ogunbamẹru ni idi tawọn ṣe pinnu ati fọwosowọpọ pẹlu Jẹgẹdẹ ni igbagbọ ati igbẹkele kikun tawọn ni ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ti agba agbẹjọro ọhun fẹẹ lọọ ṣoju.

Awọn ẹgbẹ oṣelu ti wọn gba lati sisẹ pọ pẹlu ẹgbẹ PDP ni: Accord, AA, ACP, AAC, APGA, APM, APP, NNPP, NRM, SDP ati YPP.

Leave a Reply