Ẹgbẹ oṣelu PDP lati ilẹ Ibo beere fun igbakeji aarẹ

Jọkẹ Amọri
Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ti wọn wa lati iha Iwọ Oorun Guusu ilẹ wa, iyẹn apa ilẹ Ibo ti ni niwọn igba ti ipo aarẹ ko bọ si agbegbe naa, ti awọn si ti n ṣe atilẹyin fun ẹgbẹ naa latọdun 1999, ohun to daa ju ti ẹgbẹ PDP gbọdọ ṣe ni ki wọn ri i pe apa ọdọ awọn ni qọn ti yan igbakeji aarẹ.
Ṣe latigba ti wọn ti pari eto idibo abẹle PDP, nibi ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa to wa lati ilẹ Ibo ko ti rọwọ mu ni awọn eeyan ti n woye ibi ti ẹni ti yoo ṣe igbakeji fun Atiku yoo ti wa, ti ipade loriṣiiriṣii si ti n lọ lati ri i pe wọn yan ẹni ti yoo jẹ itẹwọgba fun gbogbo ẹgbẹ atawọn araalu paapaa, ti wọn yoo si le dibo fun un.
Ṣugbọn o da bii pe laarin awọn eeyan ilẹ Ibo ati Nija Delta ni ipo igbakeji aarẹ naa yoo ja mọ lọwọ. Eyi ko sẹyin bo ṣe jẹ pe ọmọ Hausa-Fulani ni Atiku ti wọn fa kalẹ, nigba ti ẹgbẹ alatako si ti fa ọmọ Yoruba kalẹ, ko ṣee ṣe fun wọn lati tun fa ọmọ Yoruba kalẹ bii igbakeji.
Idojukọ to kan wa ninu ọrọ naa fun awọn ẹgbẹ PDP ni pe bi awọn eeyan Ibo ti n pariwo ni awọn ara Naija Delta na pariwo pe ọdọ aọn ni igbakeji aarẹ ti gbọdọ wa.
Alaga ẹgbẹ naa, Iyorchi Ayu, ti sọ pe laipẹ rara, iyẹn laarin ọjọ diẹ si asiko ti a wa yii lawọn maa kede ẹni ti yoo jẹ igbakeji aarẹ ti yoo dupo pẹlu Atiku Abubakar. O sọrọ yii lẹyin ipade to ṣe pẹlu awọn igbimọ ti wọn gbe kalẹ lati ṣamojuto ẹni ti wọn yoo fa kalẹ lati ṣoju ẹgbẹ naa gẹgẹ bii igbakeji aarẹ ati agbegbe ti yoo ti wa.
Lọsẹ to kọja ni wọn gbe igbimọ naa, ninu eyi ti awọn gomina, awọn agbaagba oṣelu atawọn igbimọ apaṣẹ ẹgbẹ naa wa kalẹ.
Iṣẹ ti wọn gbe le wọn lọwọ ni lati ri i pe wọn fa ẹni kan kalẹ ti yoo dije pẹlu Atiku titi opin ọsẹ yii.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//lephaush.net/4/4998019
%d bloggers like this: