Jide Alabi
Ki ọrọ orilẹ ede yii le lojuutu, ẹgbẹ oṣelu PDP ti ke sawọn ọmọ Naijiria lati kora jọ lati fimọ ṣọkan, ki ọjọ ọla wọn le dara ju bayii lọ.
Ọrọ ti Ààrẹ Muhammadu Buhari ba awọn eeyan orilẹede yìí sọ lọjọ ọdun tuntun ni wọn lo fa ipe ti ẹgbẹ oṣelu PDP n pe yii.
Ninu atẹjade ti akọwe ipolongo ẹgbẹ naa, Kọla Ọlọgbọndiyan, fọwọ sí lo ti sọrọ yii.
O ni bi nnkan ṣe n lọ labẹ akoso Buhari, o jọ pe orilẹ-ede to ti kùnà ninu eto idagbasoke lọrọ Naijiria fẹẹ jọ bayii, ati pe ijọba Buhari ko ni ohun gidi kan bayii mọ fun Naijiria.
Ẹgbẹ PDP sọ pe iyalẹnu nla ni ọrọ ti Ààrẹ sọ lọdun tuntun ọhun jẹ, nitori ko si ohun gidi kan nibẹ bi ko ṣe awawi ati ileri asan ti ko lanfaani kan bayii to le se fun orilẹ-ede.
Wọn ni ọrọ ti Aarẹ, Muhammadu Buhari sọ yii ti tubọ fi ìjọba ẹ han gẹgẹ bíi èyí ti ko ri ipa kankan sa mọ nipa ọrọ eto aabo, ati ọrọ ajé, bẹẹ lo jọ pe awọn nnkan ọhun ti dàrú mọ ọn lọwọ gidigidi.
Siwaju si i, wọn ni awọn idi ti ko f’ẹsẹ mulẹ to wa ninu ọrọ tó bá àwọn èèyàn orilẹ-ede yii sọ ko ṣai fihan pe lọwọ àwọn olórí ti wọn kò mọ ohun ti wọn n ṣe mọ ni Naijiria wà báyìí, paapaa lori bi wọn ṣe kùnà láti kojú awọn adaluru, ajinigbe, awọn afẹmi-ṣofo atawọn janduku agbebọnrin ti wọn n gba abule lọwọ àwọn aráàlú, tí wọn sì tún n da ẹmi awọn ọdọ ti wọn lanfaani nla ti wọn fẹẹ ṣe fún orilẹ ede yii legbodo.
Ologbodiyan sọ pe,“Ohun kan to ṣe pàtàkì tawọn eeyan n reti lọwọ Ààrẹ ni bí yóò ṣe ṣatunto sọrọ eto aabo, tí yóò sì gbé ìgbésẹ̀ tó nipọn lori awọn to fi ọrọ aabo orilẹ-ede yii ṣọ.
“Ọrọ tó wà nílẹ̀ yìí kọja ki Olori kan máa ṣawawi asán ati awọn idi ti ko fẹsẹ rinlẹ. Ohun ti a n sọ ni pe ọrọ ti Buhari ba awọn eeyan sọ lọjọ Ẹti ti tubọ fi ìjọba ẹ hàn pé orilẹ-ede Naijiria nilo olori gidi to ṣetan lati mu un tẹ síwájú ju bayii lọ.”
Bakan naa ni wọn sọ pe iyanu lo jẹ bí Ààrẹ Muhammadu Buhari ko ṣe sọ ohunkohun lori bi ijọba rẹ yóò ṣe fopin sì wahala tawọn ẹṣọ agbofinro n ko ba awọn ọdọ ti wọn n dunkooko mọ bayii lori ọrọ iwode tà ko SARS ati ikọlu to waye ni too-geeti Lẹkki, l’Ekoo.
Akọwe ipolongo ẹgbẹ naa fi kun un pe, “u gbogbo ẹ lọ, ẹgbẹ oṣelu wa rọ awọn ọmọ Naijiria ki wọn ma ṣe sọ ireti nù, ṣugbọn ki wọn lo anfààní ọdun tuntun yii lati tubọ fi ìmọ ṣọkan lati lo anfààní ti ijọba dẹmokiresi fún wọn lati fi gba Naijiria silẹ lọwọ ijọba ti ko mọ ohun tó kàn mọ bayìí.