Ẹgbẹ oṣiṣẹ kilọ fun ijọba, wọn ni wọn ko gbọdọ le awọn oṣiṣẹ ile aṣofin

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Agbarijọpọ ẹgbẹ oṣiṣẹ nipinlẹ Ekiti ti kede pe awọn ko ni i gba ijọba laaye lati le awọn oṣiṣẹ to wa nile-igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, eyi to jẹ ọrọ kan tawọn n gbọ labẹlẹ.

Ninu lẹta kan ti akọwe NLC, Comrade Taiwo Akinyẹmi pẹlu ojugba rẹ lati TUC, Lawrence Kuloogun ati Gbenga Olowoyọ lati JNC fọwọ si ni wọn ti sọ pe ileeṣẹ to n mojuto awọn oṣiṣẹ ile aṣofin fẹẹ ṣe ayẹwo kan, o si ṣee ṣe ki wọn fẹẹ fi le awọn oṣiṣẹ.

Lẹta ọhun, eyi ti wọn kọ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ni wọn fi ṣọwọ si Olori ile aṣofin, Funminiyi Afuyẹ, bẹẹ ni wọn kilọ pe ko ma gba iru igbesẹ bẹẹ laaye nitori yoo ba ajọṣẹpọ ẹgbẹ oṣiṣẹ ati ijọba jẹ.

 

 

Wọn ni ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ile aṣofin, Parliamentary Staff Association of Nigeria (PSSAN), lo ta awọn lolobo, tijọba ba si n ro iru nnkan bẹẹ tẹlẹ, ki wọn yaa tun ero wọn pa nitori ẹgbẹ oṣiṣẹ ko ni i gba ki iru ẹ ṣẹlẹ si oṣiṣẹ kankan l’Ekiti.

Wọn waa ni ọdun 2011 ni akọsilẹ awọn oṣiṣẹ ọhun ti wa nilana igbalode, ayẹwo tawọn si n gbọ pe wọn fẹẹ ṣe yii mu ifura dani.

Ṣugbọn alaga ileeṣẹ to n mojuto ile aṣofin ọhun, Ọnarebu Taiwo Ọlatunbọsun, sọ pe kayeefi ni ẹsun awọn oṣiṣẹ naa jẹ nitori ko si nnkan to jọ pe ijọba fẹẹ le oṣiṣẹ.

O ni loootọ ni ayẹwo fẹẹ waye, ṣugbọn gbogbo igba lawọn maa n ṣe iru ẹ lati mọ iye oṣiṣẹ tawọn ni ati igbeṣe ilọsiwaju to yẹ lati gbe.

Leave a Reply