Ẹgbẹ oṣiṣẹ lawọn ko fara mọ afikun owo oṣu tuntun tijọba kede

Monisọla Saka

Aarẹ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorilẹ-ede yii, Nigerian Labour Congress (NLC), Joe Ajaero, ti sọ pe ẹgbẹ awọn lodi si ẹkunwo owo-oṣu ti Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ṣe fawọn oṣiṣẹ ni ayajọ ọjọ oṣiṣẹ ku ọla.

Lasiko to n ṣe ifọrọwerọ kan l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni Ajaero ti lawọn ko le fara mọ owo-oṣu tuntun naa.

O ni owo-oṣu to kere ju lọ, iyẹn ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira, ti ijọba n ṣamulo tẹlẹ, ni titan ti de ba, ti ko si wulo mọ lati ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii.

“Inu ijọba olowo oṣu tuntun lo yẹ ka wa lonii yii. O yẹ ka ti fẹnu ọrọ jona lori iyẹn. Ijọba apapọ ti jokoo lori ọrọ naa nipasẹ awọn ileegbimọ aṣofin, ṣugbọn ọrọ naa ko so eeso rere nitori bi ijọba apapọ ko ṣe jẹ ki ipade ti wọn sun siwaju waye mọ.

“Mo lero pe ikede abosi leleyii, nitori ko si afikun owo-oṣu kankan ti ijọba kede. Fun wọn lati waa kede ẹ bayii, ọrọ to n kọ awa ẹgbẹ oṣiṣẹ mejeeji, iyẹn NLC ati TUC lominu ni”.

Nigba to n ṣalaye iye ti wọn ti fẹnu ko si gẹgẹ bii owo-oṣu oṣiṣẹ ijọba, o ni iru owo bayii kan wa fun pe keeyan maa rọwọ mu lọ sẹnu ni, owo ti ko ni i jẹ keeyan toṣi ju bo ṣe yẹ lọ lasan lo jẹ.

O ni, “Iru owo-oṣu ti a n sọ yii jẹ eyi ti yoo jẹ keeyan maa ri jẹ, ri mu. Ki i ṣe iru eyi ti yoo jẹ keeyan talaka tabi maa rare. Ki i ṣe iru owo oṣu ti yoo jẹ keeyan maa ya owo ko too le lọ sibi iṣẹ. Ki i si i ṣe iru eyi ti yoo jẹ keeyan dero ọsibitu latari airi ounjẹ gidi jẹ. Fun iru owo oṣu ti a n sọ yii, ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta ati ẹgbẹrun mẹẹẹdogun Naira (615,000), ni a n foju wo.

“Ẹ jẹ ki n sọ bi a ṣe fẹnu ko lori iye yii si wẹwẹ fun yin. Ẹ jẹ ka wo ogoji ẹgbẹrun fun ọrọ owo ile, owo ina ni tiẹ, bii ogun ẹgbẹrun, owo ina ti a ṣiro yii ki i ṣe ti isinyii ti wọn ti fowo kun un o, nitori ko sẹni to le na iru owo yii lọwọ bayii. Ẹgbẹrun mẹwaa fun owo awọn nnkan pẹẹpẹẹpẹ, bẹẹ la foju wo kẹrosiini ati gaasi ni bii ẹgbẹrun lọna mẹẹẹdọgbọn si marundinlogoji Naira.

“A wo jijẹ mimu fawọn idile ẹlẹni mẹfa si ẹgbẹrun mẹsan-an lojumọ, fun ọgbọn ọjọ, igba ẹgbẹrun ati aadọrin Naira (270,000) niyẹn jẹ. Ẹ jẹ ka wo inawo lori ilera, bii ẹgbẹrun lọna aadọta ni a ṣi fun un, niwọn igba ti ko ba ti lagbara ju, tabi ni iṣẹ abẹ ninu.

“Aṣọ wiwọ bakan naa, ogun ẹgbẹrun ni a foju sun. Eto ẹkọ, aadọta Naira ni a ṣi fun un. Emi o kan waa le sọ awọn ti wọn n fọmọ wọn sileewe aladaani o, iru iye ta a ṣi yii ko ni i le ṣiṣẹ fawọn. Bẹẹ la ṣi ẹgbẹrun mẹwaa Naira fun imọtoto ati itọju ayika.

Mo lero pe nibi ti inawo to ga tun wa ni ọrọ mọto wiwọ. Eyi waye nitori pe ọna jinjin lawọn oṣiṣẹ n gbe, nitori owo epo bẹntiroolu to si ti gbowo leri, ẹgbẹrun lọna aadọfa Naira (110,000), ni a ṣi fun iyẹn.

“Eyi lo jẹ ki owo oṣu amayerọrun (living wage) yii jẹ ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta Naira ati mẹẹẹdogun (N615,000). Mo si n fẹ ki ẹnikẹni ṣe ayẹwo ati iwadii lori ẹ boya aaye ati tọju owo pamọ yoo wa, tẹ ẹ ba n lo iru eleyii fi sanwo feeyan”.

Bẹ o ba gbagbe, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọgbọnjọ, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ owo-oṣu ati owo ọya awọn oṣiṣẹ, National Salaries, Incomes and Wages Commission (NSIWC), kede pe lati ọjọ kin-in-ni, oṣu Karun-un yii, ni ẹkunwo tuntun naa yoo gbera sọ fawọn oṣiṣẹ. Ida mẹẹẹdọgbọn si marundinlọgbọn ni wọn fi kun owo naa. Leyii to kan awọn ọlọpaa ati ologun ilẹ wa.

Leave a Reply