Adewale Adeoye
Pẹlu ọrọ tawọn alakooso ẹgbẹ oṣiṣẹ orileede Naijiria ‘Nigeria Labour Congress’ (NLC) ati ajọ ọlọja nilẹ wa, ‘Trade Union Congress’ (TUC) n sọ, ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta o le ẹgbẹrun mẹẹẹdogun Naira (625, 000) lowo ti wọn lawọn feẹ gba lọwọ ijọba apapọ bi oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii ba ti pari. Koda, wọn ni ko sohun to le yẹ ẹ rara pe kawọn maa gbowo oṣu naa, nitori pe ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira tawọn n gba gẹgẹ bii owo-oṣu oṣiṣẹ to kere ju lọwọ ijọba ko too ṣe nnkan kan rara, paapaa ju lọ lasiko ti gbogbo ọja ati owo mọto ti gbowo lori gidi bayii.
Nibi ayẹyẹ ayajọ awọn oṣiṣẹ orileede yii kan to waye niluu Abuja, ni wọn ti sọrọ ọhun di mimọ pe ki ijọba apapọ orileede yii tete ṣeto naa ni kia, ki wọn si sanwo oṣu tuntun tawọn n beere fun bayii fawọn oṣiṣẹ.
Aarẹ ẹgbẹ naa, Kọmureedi Joe Ajaero ati olori ẹgbẹ ọlọja (TUC), Ọgbẹni Fetus Osifo, bẹnu atẹ lu ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira tijọba orileede yii n san fawọn oṣiṣẹ pe ko too tọju ẹbi rara, nitori pe nnkan ti gbowo lori ju.
Wọn waa rọ Olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, pe ko tete buwọ lu aba awọn lati maa gba ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta o le ẹgbẹrun mẹẹẹdogun Naira gẹgẹ bii owo-oṣu tuntun tawọn n fẹ ki oṣu Karun-un, ọdun yii too pari.
Ajero ni, ‘Ẹgbẹ mejeeji, iyẹn ẹgbẹ oṣiṣẹ ati ẹgbẹ ọlọja ti fẹnuko laarin ara wa, ohun ta a si sọ ni pe bi ijọba orileede yii ko ba gbe igbesẹ gidi lori aba owo-oṣu tuntun ta a gbe siwaju wọn ki oṣu Karun-un, ọdun yii, too pari, awa paapaa maa gbe igbesẹ to lagbara gidi, o si ṣee ṣe ko ma tẹ awọn alaṣẹ ijọba orileede yii lọrun.