Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, ni ẹgbẹ oṣelu APC, ẹka tipinlẹ Kwara, bura fun awọn oloye ẹgbẹ tuntun niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ipinlẹ naa.
Ibura wọle ọhun lo waye ni Gbọngan Banquet, ladojukọ ile-ijọba Ilọrin, nibi ti Agbẹjọro Titus Ashaolu (SAN), ti bura fun gbogbo awọn oloye ẹgbẹ patapata.
Nigba ti Gomina Abdulrahman Abdulrasaq n sọrọ nibi ayẹyẹ ọhun, o ni iṣejọba ẹgbẹ oṣelu APC ti mu ileri ipolongo rẹ ṣẹ lẹka eto ilera, ileewe alakọọbẹrẹ, riro awọn ọdọ lagbara ati bẹẹ bẹẹ lọ. O fi kun un pe ẹgbẹ oṣelu APC ti fitan rere lelẹ nipa pipese ohun amayedẹrun faraalu, o waa ki gbogbo awọn oloye ẹgbẹ ku oriire.
Sunday Fagbemi to jẹ alaga tuntun ti wọn ṣẹṣẹ bura wọle fun sọ pe ẹgbẹ oṣelu APC ko ni gbe ijọba fawọn ojẹlu mọ laelae, tori pe ayipada rere ti araalu n reti ti n ṣẹlẹ lọwọlọwọ nipinlẹ naa. O tẹsiwaju pe gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ti wọn n fapa janu ni wọn yoo pẹtu si ninu laipẹ.