Ẹgbẹ oṣelu PDP Ọṣun lawọn ko ni i kopa ninu idibo ijọba ibilẹ ti OSIEC fẹẹ ṣe

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun ti sọ pe awọn ko ni i kopa ninu idibo ijọba ibilẹ ti ajọ OSIEC fẹẹ ṣe ni ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, nitori igbesẹ to lodi si ofin ni ajọ naa fẹẹ gbe.

Ṣaaju ni ajọ OSIEC ti kede igbaradi rẹ lati ṣeto idibo si awọn ijọba ibilẹ ọgbọn, ijọba agbegbe mejilelọgbọn ati eeria kansu meje to wa nipinlẹ Ọṣun.

Ṣugbọn ẹgbẹ PDP sọ pe igbesẹ naa jẹ ọna ti ẹgbẹ oṣelu APC tun fẹẹ gba lati ti ipinlẹ Ọṣun si oko gbese miiran ko too di pe ijọba wọn yoo kogba wọle lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii.

Adele alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Ọṣun, Dokita Akindele Adekunle, ṣalaye pe ẹgbẹ naa ko ni i darapọ mọ awọn ẹgbẹ oṣelu to ku lati gbe igbesẹ to ta ko alakalẹ ofin idibo orileede Naijiria.

O ni bo tilẹ jẹ pe ofo ọjọ keji ọja ni wọn yoo mu bọ ninu idibo ti wọn fẹẹ ṣe naa, sibẹ, ohun to mu ki awọn maa pariwo sita ni pe wọn yoo tun fi idibo ọhun ṣe mọkaruuru eto iṣuna ipinlẹ Ọṣun ni.

Adekunle sọ siwaju pe, “A n fi asiko yii gba alaga ajọ OSIEC nimọran pe ko ma ṣe yọnda ara rẹ gẹgẹ bii irinṣẹ lọwọ awọn ẹgbẹ APC lati ṣe nnkan to ta ko ofin. A ti ran awọn igbimọ lọ sọdọ rẹ lati ṣalaye ewu to wa ninu igbesẹ to fẹẹ gbe fun un.

“A ti sọ fun wọn pe ki wọn ma ṣe tẹsiwaju ninu ipinnu wọn lati ṣeto idibo yii, nitori o ta ko ofin. Atubọtan bi wọn ṣe kọ jalẹ lati ṣeto idibo yii yoo lewu pupọ.

“Fifi oju fo ipin akọkọ ati ikeji ati ila kẹrin ni abala aadọjọ (150) iwe ofin idibo lewu pupọ, nitori oun lo sọ ọ di iwa ọdaran fun oṣiṣẹ ajọ eleto idibo kankan lati tasẹ agẹrẹ si ilana ofin naa, o tun ti waa di iwa ọdaran paraku lati fi owo ijọba ṣofo lori idibo ti ko le rẹsẹ walẹ naa.

“Ireti wa ni pe awọn oṣiṣẹ ajọ OSIEC atawọn alabaaṣiṣẹpọ wọn ninu iwa aibọwọ fun ofin yoo gba ikilọ yii nitori ogun awitẹlẹ ki i pa arọ to ba gbọn.”

Leave a Reply