Oluṣẹyẹ Iyiade Akurẹ
Apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ ipinlẹ Ondo ti ni afaimọ ki Gomina Rotimi Akeredolu ma ri pipọn oju awọn to ba fi kọ lati san gbogbo owo-osu atawọn ajẹmọnu mi-in tijọba rẹ jẹ awọn oṣiṣẹ.
Ikilọ yii waye ninu lẹta kan ti adari awọn oṣiṣẹ naa fi ṣọwọ si gomina lẹyin ipade ti wọn ṣe lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja.
Awọn oṣiṣẹ ọhun fẹdun ọkan wọn han lori bi Arakunrin ṣe kọ lati tẹle adehun ti wọn jọ ṣe ninu ipade ti wọn ṣe pẹlu ijọba ninu oṣu keje, ọdun ta a wa yii.
Wọn ni lara ileri ti gomina ṣe nigba naa ni sisan osu marun-un ninu owo moda moda ti ijọba n ba awọn oṣiṣẹ yọ ati sisan owo ajẹmọnu awọn oṣiṣẹ ti ọdun 2018 lati ipele keje de ikẹtadinlogun ni kete ti owo to n ti ọdọ ijọba apapọ wa ba ti de fun oṣu keje.
Ẹgbẹ yii ni o ya awọn lẹnu pe owo-osu mẹta pere ni Akeredolu san nigba to rowo ọhun gba tan, wọn ni ṣe lo tun na biliọnu mẹjọ o dín diẹ naira, iyẹn owo atunṣe ọna tijọba apapọ da pada fun un si apo ara rẹ lai ri tawọn oṣiṣẹ ro.
Wọn fi kun un pe tijọba Akeredolu ko ba fẹ wahala, ko tete tẹle ajọṣọ awọn laarin ọjọ mẹjọ pere, bẹrẹ lati ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.