Ẹgbẹ olukọ ileewe giga fasiti fẹẹ bẹrẹ iyanṣẹlodi oṣu kan lati fa ijọba leti

Jọkẹ Amọri

Gbedeke oṣu kan pere ni awọn igbimọ ẹgbẹ awọn olukọ nileewe giga fasiti ilẹ wa ta a mọ si ASUU fun ijọba apapọ lati wa ojutuu si gbogbo awọn ẹdun ọkan wọn ti wọn ti n beere lọwọ wọn latọjọ yii wa, ti wọn ko ti i ṣe ohunkohun lori rẹ.

Ikede yii waye lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lẹyin ipade alasiko pipẹ tawọn eeyan naa ṣe ninu ọgba Fasiti Eko.

Furaidee, ọjọ kọkanla, oṣu keji yii, ni wọn fun ijọba apapọ lasiko da lati dahun sọrọ wọn.

Lẹyin tijọba ko ṣe ohun ti wọn fẹ lawọn eeyan naa bẹrẹ ipade lati ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejila, oṣu yii, lati jiroro lori ohun to kan. Ibi ipade ọhun ni wọn si wa titi di aarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ti wọn ṣẹṣẹ fẹnu ko lati lọ fun iyanṣẹlodi oṣu kan lati kilọ fun ijọba. Bi ijọba ba waa kọ ti wọn ko ṣe ohunkohun ni wọn sọ pe awọn yoo lọ fun iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ.

Gẹgẹ bi awọn olukọ naa ṣe sọ, ‘‘A fẹẹ fun ijọba lọpọlọpọ asiko lo mu ki iyanṣẹlodi ikilọ yii fẹẹ waye, pẹlu ireti pe ijọba yoo ri idi ti ko fi yẹ ki eto ẹkọ dẹnu kọlẹ lawọn ileewe giga fasiti ilẹ wa.

‘‘Obi ni awa naa loootọ, ti a si lawọn ọmọ lawọn ileewe yii, ṣugbọn pẹlu rẹ naa, a ko le maa wo ki eto ẹkọ dẹnukọlẹ lorileede yii.

‘‘Fun anfaani gbogbo eeyan ni ohun ti a n ja fun, bi eto ẹkọ ba si pada daa nilẹ wa, gbogbo wa naa la maa janfaani rẹ. Ọpọlọpọ awọn eeyan nla nla nilẹ wa ni wọn ti da si ọrọ naa, ṣugbọn niṣe nijọba kọ eti ikun si wọn.’’

O ṣe diẹ ti awọn ẹgbẹ olukọ ileewe giga fasiti yii ti n beere awọn ẹtọ kan lọdọ ijọba. Ninu nnkan bii mejila ti wọn ni awọn n beere fun, meji pere ni wọn ni ijọba ṣe ninu rẹ.

Lara ohun ti awọn olukọ naa ni ki ijọba ṣe fun awọn ni ṣiṣe atunṣe ati agbekale tuntun fun owo-oṣu wọn ati aọn ohun ti o tọ si wọn. Bakan naa ni wọn n beere pe ki ijọba ya owo sọtọ ti awọn olukọ yii yoo fi maa fi imọ kun imọ nipa iṣe iwadii, lati le maa ran awọn akẹkọọ wọn lọwọ. Wọn tun sọ pe owo gbọdọ wa fun awọn olukọ ti wọn ba n ṣiṣe iwadii to ni i ṣe pẹlu eto ẹkọ. Wọn tun beere fun owo ti wọn fi le ṣe agbedide orisiiriṣii nnkan to le mu ki eto ẹkọ rọrun fun aọn akẹkọọ.

Yatọ si eleyii, wọn ni ki ijọba pada si ọna ti wọn n gba sanwo awọn olukọ yunifasiti yii telẹ, eyi ti wọn pe ni University Transparency and Acountability System ( UTAS) yatọ si eyi tijọba apapọ n lo bayii.

Leave a Reply