Ẹgbẹ onimọto ipinlẹ Eko ya kuro lara NURTW

Adewumi Adegoke

Nitori wahala to n lọ laarin alaga ẹgbẹ onimọto Eko ati awọn alaṣẹ ẹgbẹ naa lapapọ, ninu eyi ti wọn ti jawee gbele-ẹ fun alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Eko, Musiliu Akinsanya ti gbogbo eeyan mọ si MC Oluọmọ, awọn ọmọ ẹgbẹ ẹgbẹ naa ati gbogbo oloye wọn nipinlẹ Eko ti kede pe awọn ti kuro ninu apapọ ẹgbẹ NURTW.

Nibi ipade kan ti wọn ṣe ni ile ẹgbẹ wọn to wa l’Agege, nipinlẹ Eko, ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni wọn ti kede pe Akinsanya ati gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ onimọto NURTW ti kuro ninu ẹgbẹ apapọ onimọto yii. Wọn ni gbogbo ọna ti awọn gba lati jẹ ki alaafia jọba, kawọn si yanju ede-aiyede to n lọ laarin awọn atawọn adari ẹgbẹ naa lo ja si pabo.

Wọn fi kun un pe awọn ọmọ ẹgbẹ awọn paapaa ṣewọde ifẹhonu han lọ si ọdọ Gomina Babajide Sanwoolu.

Nitori pe awọn si jẹ ẹni to bọwọ fofin, ti ko ni i fẹ ki wahala kankan ṣẹlẹ, tabi ki ohunkohun da alaafia ipinlẹ Eko ti awọn fẹran daadaa ru loun gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ naa ati gbogbo oloye ẹgbẹ yooku atawọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn wa ni ẹka to to bii igba (200) kaakiri ipinlẹ Eko pe awọn ti kuro ninu ẹgbẹ NURTW, awọn ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ naa mọ.

O ni igbesẹ ti awọn gbe yii wa ni ibamu pẹlu ofin ilẹ wa to fi aaye gba ẹnikẹni lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu tabi ẹgbẹ mi-in to ba wu u lai ṣe pe ẹnikẹni halẹ mọ ọn tabi fiya jẹ ẹ.

Bẹẹ lo lawọn ti ṣetan lati fi ipinnu awọn han si Gomina Babajide Sanwoolu, ileeṣẹ to n ri si igbokegbodo ọkọ l’Ekoo ati gbogbo ẹka yooku to ba yẹ.

Akinsanya waa rọ ijọba ipinlẹ Eko lati gba isakoso idari ọkọ nipinlẹ Eko nipa ṣiṣe idasilẹ igbimọ ti yoo maa mojuto awọn onimọto ati garaaji kaakiri to pe ni Park Management Committee, titi ti ọrọ naa yoo fi yanju, ti alaafia yoo si jọba.

O waa gba awọn ọmọ ẹgbẹ naa nimọran pe ki wọn maa ṣiṣẹ wọn lọ lai sewu, ti wọn ba si ri awọn ọlọpaa lawọn gareeji wọn, ki wọn ma bẹru, wọn wa nibẹ lati daabo bo wọn ni.

Lẹnu ọjọ mẹta yii lawọn kan ti n gbe e kiri pe MC Oluọmọ atawọn ẹgbẹ rẹ kan fẹẹ ya kuro ninu ẹgbẹ onimọto apapọ, ti wọn si fẹẹ lọọ da ẹgbẹ mi-in silẹ.

Asiko naa lawọn oloye ẹgbẹ kan pariwo pe wọn n fi tipa mu awọn lati sọ pe awọn ko ṣe NURTW mọ, ati pe ẹgbẹ tuntun yii lawọn fẹẹ maa ṣe.

Ko pẹ sigba naa ni wọn fun MC ni iwe pe ko waa sọ tẹnu rẹ, lẹyin rẹ ni wọn si rọ ọ loye alaga fun igba ti ẹnikẹni ko le sọ.

Awọn kan ti n sọ pe ọrọ ija to n lọ naa lọwọ kan oṣelu ninu. Ko si ti i sẹni to mọ ibi ti ọrọ naa yoo ja si.

Leave a Reply