Ẹgbẹ PDP Ekiti ṣepade apero lori ibo 2022

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Lopin ọsẹ to kọja ni ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP) nipinlẹ Ekiti, ṣepade apero lori bi ẹgbẹ naa yoo ṣe gbajọba lọwọ ẹgbẹ All Progressives Congress (APC) to wa lori aleefa nipinlẹ naa.

Ipade naa, eyi to waye ni Sẹkiteriati PDP to wa niluu Ado-Ekiti, lo jẹ ipejọpọ awọn akọwe ẹgbẹ lati ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa l’Ekiti ati wọọdu marundinlọgọjọ (155).

Kọmiṣanna fọrọ iṣẹ ode lasiko iṣejọba Gomina Ayọdele Fayoṣe, Abilekọ Funmilayọ Ogun, to ti di akọwe ẹgbẹ PDP bayii lo pe ipade ọhun pẹlu Ọnarebu Bisi Kọlawọle to jẹ alaga atawọn ọmọ igbimọ alaṣẹ to ku.

Ọnarebu Kọlawọle rọ awọn to wa nibi apero ọhun lati bẹrẹ eto ilanilọyẹ ati ipolongo nla lọna ti yoo jẹ kawọn eeyan mọ pe PDP ti de lati le APC kuro lori aleefa. O ni igba akọkọ niyi ti akọwe ẹgbẹ yoo pe iru ipade bẹẹ, eyi si fi han pe asiko iṣẹ ti de.

Alaga naa ni kawọn ọmọ ẹgbẹ ọhun gbagbe ọrọ atẹyinwa, ki wọn fọkan si ibo 2022, ki wọn si ṣiṣẹ pẹlu awọn alaga ijọba ibilẹ ati wọọdu wọn nitori ibo ọhun jẹ PDP logun ni gbogbo ọna.

Bakan naa ni Abilekọ Ogun fidi ẹ mulẹ pe kawọn olukopa ọhun tẹle ofin ẹgbẹ, eyi ti yoo ran ifọwọsowọpọ awọn atawọn alaga lọwọ, bẹẹ ni ki wọn maa ṣe akọsilẹ awọn igbesẹ ti wọn ba n gbe.

Leave a Reply