Ẹgbẹ PDP gbọdọ wa niṣọkan ti wọn ba fẹẹ gbajọba lọdun 2023 – Oyinlọla

Florence Babaṣọla

 

Gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, Ọmọọba Ọlagunsoye Oyinlọla, ti sọ pe o ṣee ṣe fun ẹgbẹ oṣelu PDP lati gbajọba pada lorileede yii ti gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ ba pinnu lati wa niṣọkan, ki wọn si ṣiṣẹ papọ.

Lasiko ti igbakeji gomina tẹlẹ nipinlẹ Ọyọ, Taofeek Arapaja, ẹni to n dije funpo alaga ẹgbẹ naa niha Guusu Iwọ-Oorun orileede yii, ṣabẹwo siluu Oṣogbo ni Oyinlọla ti sọ pe ẹgbẹ oṣelu APC ti ja gbogbo ọmọ orileede yii kulẹ patapata.

O ṣalaye pe afi ẹni to ba n tan ara rẹ jẹ nikan ni yoo sọ pe nnkan n lọ daadaa lorileede yii lasiko ti a wa yii, o ni ko si eyi ti ẹgbẹ APC muṣẹ ninu gbogbo ileri ti wọn ṣe fawọn araalu.

Oyinlọla ṣalaye pe gbogbo ohun ti wọn sọ pe awọn yoo ṣe lori ọrọ okoowo, ifopin si iwa ibajẹ ati jẹgudujẹra, eto aabo ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn kuna lati ṣe, ti gbogbo nnkan si n le koko si i lojoojumọ.

O ni oun nigbagbọ daadaa pe ẹgbẹ oṣelu PDP le gbajọba lọdun 2023 nitori gbogbo awọn araalu nijọba to wa lode bayii ti ṣu. Ti ifẹ ati iṣọkan ba si wa, ko le ṣoro rara.

O ni inu oun dun si bi alaafia ṣe pada sinu ẹgbẹ naa niluu Ekiti, ati pe oun n sa ipa oun lati jẹ ki ẹgbẹ naa pada bọ sipo nipinlẹ Ọṣun, to si jẹ pe didun lọsan yoo so laipẹ.

Ṣaaju ni Arapaja ti bẹbẹ pe ki awọn ti wọn jẹ aṣoju ti wọn lẹtọọ lati dibo fi ibo wọn gbe oun lọwọ. O si ṣeleri pe oun ko ni i ja wọn kulẹ ati pe gbogbo ipinlẹ ti gbodo

Leave a Reply