Ẹgbẹ PDP lo ti da wahala iṣẹ ati oṣi pẹlu eto aabo to mẹhẹ yii silẹ lasiko ti wọn fi n ṣejọba-Bamidele

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

 

Sẹnetọ to n ṣoju awọn eeyan Aarin-gbungbun Ekiti, Ọpẹyẹmi Bamidele ati aṣofin to ṣoju awọn eeyan Ariwa Ekiti tẹlẹ, Sẹnetọ Ayọ Ariṣe, ti gbeja ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) lori ipo ti Naijiria wa lọwọlọwọ.

Lopin ọsẹ to kọja tawọn mejeeji tun iforukọsilẹ ṣe lẹgbẹ APC latari eto to n lọ lọwọ lati gba awọn ọmọ ẹgbẹ tuntun wọle, ati fun awọn ọmọ ẹgbẹ tẹlẹ lati tun fontẹ lu ajọṣepọ wọn pẹlu ẹgbẹ naa. Bamidele ṣe tiẹ niluu Iyin-Ekiti, nijọba ibilẹ Irẹpọdun/Ifẹlodun, nigba ti Ariṣe forukọ silẹ niluu Ọyẹ-Ekiti, nijọba ibilẹ Ọyẹ.

Bamidele ni eto to waye ọhun yoo ran APC lọwọ lati duro sijọba lọdun 2023, ko si yẹ ki eto naa fa ariyanjiyan latari bi awọn kan ṣe sọ pe ifowoṣofo ni. O ni orukọ lasan lawọn eeyan n kọ, ko si owo ti wọn n na, eyi si fi han pe ẹgbẹ eleto ni APC.

Bamidele ni asiko ti to ki ẹgbẹ naa tun di aayo awọn ọmọ ilẹ yii pẹlu agbeyẹwo ọrọ iṣẹ ati oṣi, ainiṣẹ ati eto aabo to mẹhẹ, eyi to jẹ wahala to ba ilẹ yii. Ṣugbọn o ni ọrọ naa ki i ṣe ọrọ oni, ẹgbẹ People’s Democratic Party (PDP) lo ti da a silẹ latari ọdun mẹrindinlogun ti wọn fi ṣejọba.

Ninu ọrọ Ariṣe, o ni APC ki i ṣe ẹgbẹ lo buru bi awọn eeyan ṣe n sọ, eyi lo si fa bi iroyin ṣe n lọ pe minisita fọrọ ọkọ ofurufu tẹlẹ, Fẹmi Fani-Kayọde, fẹẹ darapọ mọ ẹgbẹ naa.

Ariṣe ni bi Fani-Kayọde ṣe n bu Aarẹ Muhammadu Buhari ko sọ ọ di eeyan buruku, ko si sọ ọ di ọta APC, nitori ọrọ oṣelu ni, eeyan si le sọ ẹdun ọkan ẹ nigbakigba.

 

 

 

Leave a Reply