Ẹgbẹ to dara ni ẹgbẹ awa ajẹ ati emere, awọn adari ẹsin lo n ba wa lorukọ jẹ – Oyelọla Ẹlẹbuibọn

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Alakooso ẹgbẹ awọn ajẹ ati emere nipinlẹ Ọṣun, Oloye (Iyaafin) Oyelọla Ẹlẹbuibọn, ti ṣapejuwe ẹgbẹ ajẹ ati emere gẹgẹ bii ẹgbẹ ti yoo mu idagbasoke ba awujọ ti awọn eeyan ba bẹrẹ si i fojuure wo o.

Lasiko ayẹyẹ ọdun ẹgbẹ naa, alakọọkọ iru ẹ, ti wọn ṣe ni ile Araba Awo ilu Oṣogbo, Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn, ni obinrin naa ti sọ pe pataki ayẹyẹ naa ni lati jẹ ki awọn eeyan mọ pe ẹgbẹ naa ki i ṣe ẹgbẹ buburu gẹgẹ bi awọn kan ṣe maa n bu ẹnu atẹ lu u.

Oyelọla Ẹlẹbuibọn ṣalaye pe awọn olori ẹsin ni wọn sọ ẹgbẹ naa lorukọ buburu, eleyii to n mu ifasẹyin ba ọpọlọpọ nnkan lorileede yii.

O waa ke si gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ lati duro gbọingbọin ninu nnkan ti wọn gbagbọ, ki wọn ma ṣe faaye gba ẹnikẹni lati fi ọwọ rọ wọn sẹyin.

Ninu ọrọ rẹ, Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn, sọ pe ko si ẹni to wa laye ti ko ni ẹgbẹ kan tabi omi-in, o si dara ki onikaluku tete mọ ẹgbẹ tirẹ atawọn etutu to tọ si i lati le mu irin-ajo igbedide ẹni kọọkan ya kankan.

 

3 thoughts on “Ẹgbẹ to dara ni ẹgbẹ awa ajẹ ati emere, awọn adari ẹsin lo n ba wa lorukọ jẹ – Oyelọla Ẹlẹbuibọn

  1. Iro paraku ni wipe egbe aje tabi emere je egbe rere tabi egbe ti oseni ni afani. Aya mi je emere. Bi mo se so yi opolopo ise ibi ni oti se. Ese mi ko ni yanju. Gbogbo ibi ti mo lo ni won ni wipe emere alakisa ni iyawo mi. Kilode ti ko fi egbe emere e ran ise mi lowo. Ko si ohun ire kan ti aje tabi emere ni lati fun eniyan. Iran ise esu ni won. Iya aje ti o pa gbogbo awon omo e. Ki ni ere e.

    1. Orisirisi egbe Lowa…egbe emere to wa to 21 si 23.ikan ninu awon egbe buburu ni egbe emere alakisa,emere ori atan lati abiku. Kosi ile olola to won ma wo ti ile na o ni da’ahoro.
      Ti e ba se ayewo lori e finifini. Ohun ti mo n so, a ye yin.

  2. Ki Olorun gba wa lorilede yii,niru akoko to ye ki gbogbo ke pe Olorun eleda lati yonu si wa.Awon kan tun ko ara won jo nipinle ti a ro pe iberu Olorun wa pe aje ati emere ni won nigba ti won ro pe won le gbogun ti ihinrere ni agbaye,ti won ti ilekun soosi ko si eni to let dina mo awa to je omo lehin tooto.Soosi ni won tilekun e mo iye to won ti njosin lati lgba.Gbogbo won ni yii lati mu ikede egbe won Jade awa ti mo tele pe nkankan nbo lehin isele arun buburu yii. Gbogbo awa kristieni ji giri loju oorun wa lati otito oro Olorun fun awon okan ti won segbe yii.Ohun ti mo mo ni pe Olorun maa la orilede yii ati agbaye koja.ENI TI OLORUN MO.

Leave a Reply