‘Ẹgbẹrun lọna ọgbọn eeyan lo ni arun HIV nipinlẹ Ọṣun’

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Alakooso agba fun orileede Amẹrika ni Naijiria, Will Stevens, ti sọ pe akọsilẹ awọn eeyan to to ẹgbẹrun lọna ọgbọn (29,936) ni wọn ni arun HIV nipinlẹ Ọṣun. O ni pẹlu afihan yii, gbogbo araalu gbọdọ dide lati gbogun ti arun buruku yii.

Stevens ke si ijọba ipinlẹ Ọṣun, awọn oniṣegun oyinbo ati awọn ẹgbẹ ti ko rọgbọku le ijọba lati bẹrẹ igbesẹ ti yoo fopin si itankalẹ arun naa.

Lasiko ti alakooso agba naa n ṣe ifilọlẹ eto kan lori itọju arun HIV, eyi ti Excellence Community Education Welfare Scheme (ECEWS) ṣagbatẹru rẹ, to waye ni sẹkiteriati ijọba, niluu Oṣogbo, lo sọrọ yii.

O ni ọpọlọpọ awọn araalu ni wọn ko ti i mọ boya awọn ni arun naa tabi awọn ko ni i, idi niyẹn ti ijọba fi gbọdọ tubọ tẹra mọ eto ayẹwo, ki awọn ti wọn ba ni arun naa le bẹrẹ itọju kiakia.

Stevens fi aidunnu rẹ han si bo ṣe jẹ pe nnkan bii ẹgbẹrun mẹtala awọn ti wọn ni arun yii nipinlẹ Ọṣun ni wọn ko ti i bẹrẹ gbigba itọju.

O ni awọn nilo ifọwọsowọpọ ijọba, awọn ọlọpaa, awọn ajafẹtọ ọmọniyan atawọn ti wọn nifẹẹ lati ba wọn ṣiṣẹ papọ lati le fopin si arun HIV nipinlẹ Ọṣun.

O ni arun HIV ki i ṣe iwe iku, idi niyẹn ti ilanilọyẹ fi gbọdọ wa lati le jẹ ki awọn araalu finu-findọ lati jade fun ayẹwo, ki awọn to ba si ni i bẹrẹ itọju loju-ẹsẹ.

Ninu ọrọ rẹ, Gomina ipinlẹ Ọṣun, ẹni ti Igbakeji rẹ, Ọmọọba Kọla Adewusi, ṣoju fun ṣalaye pe ọfẹ ni itọju awọn to ba ni arun HIV nipinlẹ Ọṣun.

O ni pẹlu iranlọwọ awọn ajọ bii ECEWS, PEPFAR ati ibudo to n ṣekawọ itankalẹ arun, itọju awọn alarun HIV ti yatọ gidigidi, bẹẹ ni awọn ti wọn n ran ijọba lọwọ lati fopin si itankalẹ rẹ n pọ si i.

Leave a Reply