Ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un eeka oko irẹsi, agbado, ni omiyale bajẹ ni Pategi

Stephen Ajagbe, Ilorin

Olori abule Kpata-Gbaradogi, niluu Pategi, Alhaji Mohammed Tsadu, ni o kere tan, ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan eeka oko irẹsi, agbado pẹlu ọka-baba ni iṣẹlẹ omiyale bajẹ lọsẹ to kọja.

Abule Kpata-Gbaradogi ti ko ju bii kilomita mẹta si aarin ilu Pategi ni omiyale naa sọ di odo pẹlu bo ṣe gba gbogbo aarin ile ati adugbo tan, to si mu kawọn araalu maa lo ọkọ oju omi lati maa fi rin.

Tsadu ni ile bii ọgọrun-un kan lo ṣi wa laarin omi, iṣẹlẹ naa si ti sọ ọpọlọpọ di alainile lori bayii.

Mohammed Jiya toun jẹ Tsowa ti Tsadu ni iṣẹlẹ omiyale ko ṣẹṣẹ maa ṣẹlẹ niluu Pategi, ọdọọdun lo maa n waye nibẹ, ṣugbọn ti ọdun yii tun ga ju tawọn ti ẹyin lọ, iru ẹ ko ṣẹlẹ ri latigba tilu ọhun ti wa.

O ni bii ole loru ni omiyale ọdun yii ṣe wa, to si wọ ile awọn eeyan lati ko wọn lẹru lọ, eyi ti ko yọ

awọn ileewe, ileewosan atawọn ibudo tabi dukia ijọba mi-in bii opo-ina, omi-ẹrọ ati bẹẹ lọ silẹ, gbogbo ẹ lo bajẹ patapata.

Mohammed ni bo tilẹ jẹ pe omiyale naa ko pa eeyan kankan labule naa, ṣugbọn o ti dina ijẹ wọn pẹlu oko to bajẹ. O waa rọ ijọba atawọn ajọ tọrọ kan lati ran wọn lọwọ nipa ipese ounjẹ, omi to ṣee mu atawọn oogun.

Caption: Iṣẹlẹ omiyale Pategi; Awọn olori ilu naa

 

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Pasitọ Chibuzor fun awọn obi Deborah ni ile fulaati mẹrinla atawọn ẹbun mi-in

Monisọla Saka O da bii pe iku Deborah, ọmọbinrin ti awọn awọn kan juko pa, …

Leave a Reply

//zeechumy.com/4/4998019
%d bloggers like this: