Ẹgbẹrun marun-un iwe ẹsun awọn ajagungbalẹ la ri gba laarin ọdun kan aabọ- Sanwoolu

Faith Adebọla, Eko

Gomina Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu ni inu oun ko dun, ara si n fu oun sawọn oṣiṣẹ ẹka to n ri si ọrọ atunto ilu Eko (Ministry of Physical Planning), o lawọn ni wọn o ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ, ti ojo iwe ẹsun loriṣiiriṣii fi n rọ sọdọ ijọba Eko, o lo ti ju ẹgbẹrun mẹrin o le ọgọrun-un mẹjọ iwe ẹsun tawọn ti ri gba laarin oṣu mejidinlogun pere, ọpọ lo si da lori wahala awọn janduku ajagungbalẹ ti wọn tun n pe ara wọn ni ‘Ọmọ Onilẹ’.

Nibi apero ati ipatẹ awọn olokoowo ile kikọ (Lagos Real Estate Market Place Conference and Exhibition), akọkọ iru rẹ nipinlẹ Eko, eyi to waye ninu Eko Hotel, Ikoyi, ni Sanwoolu ti sọrọ ọhun. O ṣekilọ fawọn oṣiṣẹ ẹka ijọba to n ri sọrọ atunto naa pe ki wọn yẹ ara wọn wo, tẹnikẹni ba n gba owo ẹyin, ti eyi si n fa awọn aṣeyọri ijọba Eko nipa ọrọ ilẹ ati ile gbigbe sẹyin, aṣiri irufẹ ẹni bẹẹ maa tu, ọnitọhun yoo si fẹnu fẹra bii abẹbẹ.

O ni lara awọn iwe ẹsun naa fihan pe awọn kan ti wọn n ṣiṣẹ ni ẹka ileeṣẹ tọrọ yii n fawọn eeyan ni iwe aṣẹ ile kikọ lorukọ ijọba, ti wọn si n ko awọn eeyan ọhun si yọọyọọ nigba tijọba ba de lati wo awọn ile ti ko bofin mu naa danu.

Yatọ si tọrọ awọn janduku ọmọ onilẹ (ajagungbalẹ), lara aroye to wa ninu awọn iwe ẹsun mi-in ni iṣoro bi ijọba ṣe maa n pẹ ki wọn too fawọn eeyan laṣẹ ile kikọ, ati gbigba iwe oni-n-kan lori ilẹ eeyan.

Abilekọ Kẹhinde Taiwo lati ẹka to n gbogun ti iwa ajagungbalẹ nipinlẹ Eko sọ pe nnkan bii ẹgbẹrun meji awọn iwe ẹsun tijọba ri gba lawọn ti ṣiṣẹ le lori, tawọn si ti yanju awọn ẹsun naa, bo tilẹ jẹ pe awọn yoo tubọ tẹra mọṣẹ ju tatẹyinwa lọ, gẹgẹ bi Sanwo-Olu ṣe sọ.

Leave a Reply