Ẹgbẹrun marundinlọgọta naira la maa san fun oṣiṣẹ to kere ju lọ l’Ekoo – Sanwo-Olu

Faith Adebọla, Eko

Atẹwọ ayọ rẹpẹtẹ lo rọjo lọjọ Abamẹta, Satide yii, nibi ayẹyẹ ayajọ awọn oṣiṣẹ to waye niluu Eko. Eyi waye lori ileri ti Gomina Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu ṣe fun wọn pe ẹgbẹrun marundinlọgọta naira (#55,000) nijọba ipinlẹ Eko yoo maa san fun oṣiṣẹ to gbowo kere ju lọ nipinlẹ ọhun, dipo ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira (#30,000) tawọn oṣiṣẹ n ja fun.

Nibi ayẹyẹ naa to waye ni papa iṣere ti wọn sọ lorukọ Mobọlaji Johnson (Mobọlaji Johnson Stadium), Sanwo-Olu ni oun mọ riri ipa ribiribi ti awọn oṣiṣẹ n ko ninu eto iṣejọba, ipawo-wọle labẹle ati igbaye-gbadun araalu, o ni oun si mọ bi arun Korona to fẹju kankan mọ awọn orileede agbaye lọdun to kọja, titi kan ipinlẹ Eko, ṣe ṣakoba fun ọrọ-aje ati okoowo nipinlẹ ọhun.

O ni ta a ba wo o daadaa, ẹgbẹrun lọna ọgbọn ko too na nipinlẹ Eko, owo naa o debi kan, idi niyi toun ati igbimọ iṣakoso oun fi fori kori, tawọn si ronu iye to gbe pẹẹli lati san fun oṣiṣẹ to gbowo kere ju lọ, awọn si fẹnu ko si ẹgbẹrun marundinlọgọta naira.

Yatọ si ti owo, Sanwo-Olu tun ṣeleri pe laarin oṣu diẹ si i, awọn eto tawọn n ṣiṣẹ le lori lọwọ maa pese iṣẹ to din diẹ ni ẹgbẹrun lọna irinwo fawọn ti ko niṣẹ lọwọ l’Ekoo. Bẹẹ latẹwọ ayọ tun sọ lati dupẹ lọwọ gomina.

“Afojusun wa ni lati pese iṣẹ, o kere tan, a maa pese ẹgbẹrun lọna irinwo o din marun-un (395,000) lawọn ẹka ati ileeṣẹ ti wọn ti nilo oṣiṣẹ pupọ si i nipinlẹ Eko, eyi ki i ṣe ileri asan, oṣu diẹ si i la maa bẹrẹ.

Bakan naa, a n ṣe gbogbo ohun ta a le ṣe lati fun awọn ọdọ wa ni ipilẹ rere fun ọjọ ọla igbesi aye wọn. Lai ka bi ajakalẹ arun Korona ṣe ko aarẹ ba ọrọ-aje si, a o jawọ ninu fifun awọn ọdọ ẹgbẹrun mẹrin (4,000) ni idalẹkọọ lori awọn okoowo ati iṣẹ ọwọ ti wọn le maa ṣe jẹun, a si n fowo ran wọn lọwọ bi wọn ṣe n pari idalẹkọọ wọn titi dasiko yii.

“Tẹ ẹ ba ṣakiyesi, a ti n ri awọn waya mọlẹ kaakiri adugbo ati opopona lati pese intanẹẹti to ja geere ju lọ laipẹ, idi si ni pe ọpọ awọn ẹka ileewe, ileewosan, ọfiisi, ile gbigbe, eto irinna maa bẹrẹ si i lo imọ ẹrọ igbalode ati eto ayelujara lati ṣe ọpọ nnkan bii ti oke okun. Eyi maa mu ki igbe-aye ati iṣẹ ọba tubọ rọrun si i.

Bakan naa ni Sanwo-Olu tun sọ pe ijọba maa fi ilẹ hẹkita mẹwaa tọrẹ fun ajọ awọn oṣiṣẹ NLC (Nigeria Labour Congress) ati TUC (Trade Union Congress) lati fi kọle tawọn oṣiṣẹ maa maa gbe.

Leave a Reply